'A ń sa ipá wa láti dẹ́kun ìwà ìjẹkújẹ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà'

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹ-ede Naijiria, EFCC, sọ pe eeyan mẹtadinlaadọta o le ni ẹgbẹta l'awọn ti ran lọ sẹwọn laarin oṣu kọkanla si asiko ti a wa yii lori ẹsun ṣiṣowo baṣubaṣu.
Ọgbẹni Samin Amadin, to jẹ olori ẹka ilanilọyẹ ati itaniji fun ajọ EFCC, ṣalaye nilu Abuja pe nipasẹ ilakaka ajọ ọhun, ọkan o jọkan awọn agbaagba lẹnu iṣẹ ologun, agbẹjọro, adajọ atawọn oloṣelu gbogbo ni wọn n kawọ pọnyin rojọ l'awọn ile ẹjọ kaakiri fun ẹsun jẹgudujẹra.
"Laarin ọdun mẹta, ko din ni ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira ti ajọ naa ti gba pada lọwọ awọn to ko owo ilu jẹ"
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọgbẹni Amadin ni ohun to dara ni bi awọn ọdọ lorilẹ-ede Naijiria pẹlu ti ṣe bẹrẹ si ni da si igbesẹ ati ijiroro pẹlu ijọba lori gbigbogun ti iwa jẹgudujẹra.
O ni ajọ EFCC yoo tẹsiwaju lati maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹgbẹ ọdọ lori riro igbesẹ gbigbọgun ti iwa ibajẹ lagbara.








