Iléesẹ́ ológun: 300,000 ọta ìbọn la gbà ní ìpínlẹ̀ Ògùn

Ọ̀pọ̀ ọta ìbọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Àwọn èèyàn kan ló sín àwọn agbófinró ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ nípa àwọn onísẹ́ ibi náà,

Ọ̀wọ́ kọkànlélagọ́rin iléesẹ́ ológun ní Nàíjíríà kéde lọ́jọbọ pé òun ti sẹ́bùrú ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́ta tó kún fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ọta ìbọn ní agbègbè Ìgbógílà-Ìlárá ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Olùdarí ọ̀wọ́ kọkànlélọ́gọ́rin iléesẹ́ ológun náà, Ọ̀gágun Enobong Udoh, ẹ́ni tí Ọ̀gágun Olusẹgun Ọlatunde sojú fún, ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí fáwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Èkó.

"Ọ̀wọ́ kọkànlélagọ́rin iléesẹ́ ológun pẹ̀lú àjọ́sepọ̀ àwọn agbófinró la jọ sẹ́bùrú àwọn ọkọ àkẹ́rù tó kó ọ̀pọ̀ ọta ìbọn ní déédé aago mẹ́ta ku ìsẹ́jú méjì òru Ọgbọ̀jọ́ osù karùn-ún, ọdún 2018. Abúlé Balógun ní òpópónà Ìgbógílà-Ìlárá ní ìpínlẹ̀ Ògùn, lọwọ́ ti tẹ àwọn ọkọ̀ náà tí nọ́nbà wọn jẹ́ Anambra, AAH 409 ZV, Lagos, BDG 782 XU àti Lagos, GGF 88 XU."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Abimbọla Kazeem: Hábà! Ṣé ìwọ ti sáré pé ọmọ ọdún 40 ni?

Ọ̀gágun Ọlatunde fi kun pé ní kété táwọn awakọ̀ àtàwọn ìsọmọgbè wọn kófírìí ikọ̀ agbófin náà, ni wọn bá ẹsẹ̀ wọn sọ̀rọ̀, tí àwọn sì ti ń tanná wádìí wọn àti àwọn èèyàn tó leè jẹ́ onígbọ̀wọ́ wọn.

Ò sàlàyé pé àwọn èèyàn kan ló sín àwọn ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ nípa àwọn onísẹ́ ibi náà, tó sì gbósùbà fáwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ògùn àti Èkó fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn agbófinró.