Òfin tuntun: Ọmọ ọgbọ̀n ọdún lè dupò ààrẹ báyìí

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti bu ọwọ́ lu àbádòfin tì ó fààyè gba àwọn ọdọ́ láti du ipò kípò tí ó bá wù wọ́n.
A gbọ́ pé ààrẹ bu ọwọ́ lu àbádòfin náà, ninu gbọ̀ngàn ìpàdé ìgbìmọ́ aláṣe tí ó wà ní ilé ààre, Aso Rock, ní Abuja ní Ọjọ́rú.
Ẹ ó rántí pé ààrẹ ti sọ ní àyájọ́ ọjọ́ ìjọba tiwantiwa ni ọjọ́ Ẹtì pé, oun yóò buwọ́ lu àbádòfin náà ní láìpẹ́ yìí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọdún tó kọjá ni Ìgbìmo Aṣòfin Àpapọ̀ gba àbádòfin náà wọlé, láti ṣe àyípadà sí àwọn abala ìwé òfin orílẹ̀-èdè Naijiria, èyítí yóò gé ọjọ orí ati du ipò ààrẹ láti ogójì ọdún sí ọgbọ̀n ọdún.
Òfin náà yóò gé ọjọ orí ati du ipò gómìnà àti sẹ́nétọ̀ láti ọdún márùnlélọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n, ọjọ́ orí àwọn tí o lè dupò aṣojú-ṣòfin láti ọgbọ̀n ọdún sí mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY








