Iléẹjọ́: Nyame jẹ̀bi ẹ̀sùn lílu owó Taraba ní póńpó

Oríṣun àwòrán, @abati1990
Ilé ẹjọ gíga kan nílu Abuja ti dajọ ẹwọn ọdun mẹ́rìnlá fún Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Taraba, Ogbeni Jolly Nyame.
Ilé ẹjọ ní Nyame jẹbi ẹsùn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ẹsùn mọ́kànlélọ́gbọ̀n ti won fi kan.
Awọn ẹsun naa nii sẹ pẹlu lilu ọwọ ijoba ní pónpó nígbà ti o je Gómìnà ni ìpínlè Taraba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Adájọ Adebukola Banjoko dajọ ẹwọn mẹrin otooto fún-un, lẹyìn tí wọn fìdí ọrọ múlẹ pé o gba ribà, tọ sí se owo ilu ti wọn fi si ikawọ rẹ basu-basu.

Oríṣun àwòrán, EFCC Facebook
Nyame yóò ṣe ẹwọn ọdun mẹrinla náà àyàfi tí ilé ẹjọ gíga mii ba yí ìdájọ náà padà.
Àjọ tí ó ń kojú ìwà jẹgúdújẹrá lo fẹsun kàn Nyame pé o lu owo 1.64 biliọnu náírà ní pónpó.








