51595735Ọkùnrin kan rèé tó gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ lẹ́yìn tó fa igbó yó

Igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images / BBC

Iroyin kan ti o jade lo ṣàfihàn pé ọkùnrin kan, ẹni ọdún mẹ́tàlélógún gé okó rẹ̀ lẹ́yìn tí igbó tó fà yí i lórí.

Iroyin naa tí Journal of Medical Case Report gbé jáde ní ọkùnrin ará Thailand náà tó ti n mu igbo fun ọdún méjì kó tó fi igbo mimu kalẹ̀ tó sì padà sídìí rẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́ta.

Wọ́n ní lẹ́yìn wákàtí méjì tó mu gírààmù méjì ni okó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní le, tí nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn ún.

Kini o wa selẹ̀ sii leyin naa?

Bákan náà ló ní ó jọ pé okó òun yàtọ̀ sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀, tó sì rò wí pé òun le mú àdínkù bá ìnira tó ń kó bá òun, ló bá fa abẹ yọ láti gé kúrú.

Àkọlé fídíò, 'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'

Ìjábọ̀ náà ní lẹ́yìn wákàtí méjì tí ẹ̀jẹ̀ kò dá ni ọkùnrin náà di èrò ilé ìwòsàn.

Àwọn Dókítà ní àwọn kòkòrò ti wọ èyí tó gé kúrò, tí èyí tó kù lára rẹ̀ kò sì ju sẹ̀ǹtímítà méjì lọ mọ́ tí ó sì ti ge kọjá àtúnṣe.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Bawo ni aago ara rẹ̀ se wa ri bayii?

Bákan náà ni wọ́n ní ara rẹ̀ ti ń balẹ̀ lẹ́yìn tó ti ń gba ìtọ́jú.

Onímọ̀ tó ṣaájú ìwádìí náà, Nantanan Jengsuebsant ní irú ohun tó ṣe ọkùnrin ọ̀hún kìí sábà wáyé lọ́pọ̀ ìgbà àti pé káàkìri ayé ni igbó ti jẹ́ ṣíṣe àmúlò.

Ìroyin náà tẹ́síwájú pé lára àwọn ohun tí igbó máa ń fà fún àgọ̀ ara náà ní orí yíyí.