Osun 2022 elections: Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè fún PDP

Ademọla Adeleke ni awọn igun to ṣe eto idibo abẹnu ni papa iṣere ilu Oṣogbo kede gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo gomina nipinlẹ Ọṣun.PDP Osun ti kéde Omooba Dotun Babayemi ní ọmọ oyè igun kéjí
Akọsilẹ onka awọn oludibo jẹ : 1,916.
Bayii ni abajade eto idibo naa ṣe lo;
1. Ademola Adeleke - 1,887
2. Dele Adeleke - 01
3. Akinbade Fatai - 00
4. Dotun Babayemi - 00
5. Akin Ogunbiyi - 00
6. Sanya Omirin - 04
Onka awọn ibo ti ko kẹsẹjari jẹ; 24.
- Timothy Adegoke: Raheem Adedoyin ní káwọn òṣìṣẹ́ Hòtẹ́ẹ̀lì òun fi Bíbélì búra pé wọ́n ò ní tú àṣírí
- Iléẹjọ́ yọ gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi, igbákejì rẹ̀ nípò
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Sunday Igboho kò sì lè kúrò ní Benin Republic, sùgbọ́n ó tí kúrò ní àhámọ́ lọ gba ìtọ̀jú nílé ìwòsàn níbẹ̀- Agbẹjọ́rò Sunday Igboho
- Àsìkò ti tó fún wa láti gba ìpínlẹ̀ Ọṣun padà lẹ́yìn ọdún kejìlá ti a tí ń se ẹgbẹ́ alátakò- Alága PDP Ọṣun
Kini awon igun keji se ati pe tani wọ́n kede lati dije dupo PDP ni Osun?
Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ni wọn kede gẹgẹ bi i ọmọ oye ni igun ikeji ti eto idibo abẹnu PDP ti waye nipinlẹ Ọṣun.
Babayẹmi jawe olubori pẹlu onka 1,781.
Bayii si ni onka awọn oludije to ku ṣe lọ:
Dr Akin Ogunbiyi; 23
Sanya Omirin; 16
Fatai Akinbade; 28
Dele Adeleke; 32.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Kini o ti koko sẹlẹ̀ sẹ́yìn?
Adeleke, ìbátan Davido, àwọn mẹ́ta míì yọwọ́ nínú eré ìje sí ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, ìdí rèé
Eeyan mẹrin ninu awọn mẹfa to n dijẹ ninu ẹgbẹ oṣẹlu PDP ipinlẹ Ọṣun ti yọwọ ninu ibo naa bayii.
Laarin wakiti diẹ si ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọṣun ni eeyan mẹrin lara awọn mẹfa ọtọọtọ to n dije du ipo ọmọ oye ninu ẹgbẹ oṣelu naa kede wipe awọn ti yọ ọwọ ninu eto naa.
Akọsilẹ awọn eeyan mẹfa to gba fọọmu idije naa ni:
"Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2018, Sẹnetọ Ademọla Adeleke,
Dr Akin Ogunbiyi,
Họnọrebu Sanya Omirin,
Alhaji Fatai Akinbade,
Ọmọọba Dọtun Babayẹmi
Dele Adeleke.
Awọn mẹrin ti wọn ti fi idi ọrọ mulẹ wipe awọn ko ṣe mọ ni;
Dr Akin Ogunbiyi,
Họnọrebu Sanya Omirin,
Alhaji Fatai Akinbade
Dele Adeleke.
Nibayii, ifigagbaga fun ipo ọmọ oye ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP wa laarin Sẹnetọ Ademọla Adeleke ati Ọmọọba Dọtun Babayẹmi.
Lonii ọjọ kẹjọ osu kẹta ọdun yii si ni eto idibo naa n waye ni gbọngan nla iṣere ti ilu Oṣogbo,'Oṣogbo township stadium', gẹgẹ bi alaye ti alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Sunday Biyi ṣe fun BBC Yoruba.
Jakejado awọn ijọba ibilẹ ọgbọn to n bẹ n'ipinlẹ Ọṣun ni awọn aṣọju ti wọn yan yoo ti wa dibo fun ẹni ti o wu wọn laarin eeyan meji to n ta kangbọn.
Saaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣe ileri wi pe aabo to peye yoo wa nibi eto idibo naa.
Ninu atejade ti o to awon oniroyin lọwọ nilu Oṣogbo, Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Olokode fi idi ọrọ mulẹ pe eto aabo yoo wa saaju, lọjọ ati lẹyin idibo naa ni ibamu pẹlu ilana eto idibo ọdun 2010.
Ileeṣẹ ati awọn ẹṣọ aabo mii yoo ṣiṣẹ pọ lati ri i daju wi pe ohun gbogbo lọ bo ṣe yẹ.
Kọmisana parọwa si awọn eyan ilu lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai tapa si ofin.
Dele Adeleke: Mi ò díje du ipò gómìnà mọ́
Ibatan gbajugbaja olorin takasufe, Davido, iyẹn Dele Adeleke ti yọ ọwọ kuro lawo idije sipo gomina ipinlẹ Osun ninu eto idibo to n bọ lọna.
Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin niluu Osogbo lo ti fi ikede naa sita.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ naa ko ṣeyin ipinnu rẹ lati tẹle ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa f.un itẹsiwaju ẹgbẹ.
O ni "Ipinnu mi ko ṣẹyin bi gbogbo wa ṣe maa fọwọsowọpọ lati kopa ninu eto idibo abẹnu ki a si ṣaṣeyọri."
"Mo Gbagbo ninu igbẹsẹ ti ẹgbẹ gbe ati igbagbọ pe wọn yoo ko wa de ebute ogo."
"Fun idi eyii, mo ti sọ fun awọn adari ati gbogbo awọn alatilẹyin mi pe mi o ni dije du ipo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo to n bọ yii mọ."
"Mo gbe igbesẹ yii lọna ati ṣe ohun ti awọn adari ẹgbẹ n fẹ."
Ẹwẹ, atẹjade kan lati ọdọ awọn olori ẹgbẹ ọhun fi han pe ọmọba Dotun Babayemi ni wọn n ṣatilẹyin fun, wọn si ti rọ gbogbo awọn oludije to ku lati gbaruku tii.
Ta ni Dele Adeleke?
Ọdun 1972 ni wọn bi Bamidele David Adeleke, ọmọ ipinlẹ Osun si ni.
O jẹ ibatan si gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, o tun jẹ ibatan si Ademola Adeleke ti ọpọ eeyan mọ si 'Dancing Senator.'
O kawe nipa imọ iṣiro, Accountancy, ni ile ẹkọ gbogboniṣe ilu Ibadan, lẹyin naa lo lọ kawe siwaju si ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ibadan kan naa, UI, ko to tẹsiwaju lati ṣe MBA ni fasiti Obafemi Awolowo ni Ile Ife, OAU.
Dele ṣiṣe ni oniruru ileeṣẹ ko to di oloṣelu, lara awọn ibi to ti ṣiṣẹ ni ile ifowopamọ Liberty Merchant Bank Limited, Standard Trust Bank ati Pacific Merchant Bank Limited.
O wa lara awọn to duro digbi lẹyin ibatan rẹ, Ademola Adeleke lasiko eto idibo ọdun 2018, amọ Dancing Senator fidi rẹmi ninu eto idibo ọhun.
Akin Ogunbiyi kéde pé òun kò díje dupò gómínà mọ́ ní abẹ́ PDP Osun

Oríṣun àwòrán, @Akin Ogunbiyi
Idibo eni ti yoo dije dupo gomina ni ipinle Osun ku ọla ni Omowe Akin Ogunbiyi bẹ̀rẹ̀ orin mi o se mọ́.
Wakati perete lo ku ki idibo abenu ẹgbẹ́ oselu PDP iyen Peoples Democratic Party, PDP ti ipinlẹ̀ Osun bẹrẹ̀ bayii.
Sugbọ́n si iyalẹ́nu gbogbo eniyan ni Omowe Akin Ogunbiyi, okan gboogi lara awọn to n dije dupo naa ba kede pe oun ko se mọ́.
Akin Ogunbiyi se ikede naa nile olu ipolongo rẹ̀ to wa ni agbegbe Ogo Oluwa ni opopona marose Gbongan si Ibadan nilu Osogbo to je Olu ilu ipinle Osun to wa ni guusu iwo oorun Naijiria.
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀
- Wọ́n ti rí òkú obìnrin ẹni ọdún 22 tó dàwátì nínú ọkọ̀ BRT l'Eko
- Ọkọ̀ tó rìn gba "one way" gbá ọmọ ìyá mẹ́rin lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo l'Eko, ọ̀kan kú
- Odindi ọdún mẹ́ta ni ọkọ mi ti ń fipá bá ìbátan mi ọmọ òrukàn ọdún mọ́kànlá lò pọ̀
Saaju ni Alaga egbẹ́ oselu PDP ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nipa eto idibo naa pe:
Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ l'ọjọ Aje nilu Ọṣogbo saaju ẹto idibo abẹnu ẹgbẹ naa ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹjọ oṣu kẹta ọdun 2022, Biyi ni alaafia ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa n'ipinlẹ Ọṣun.
O ni bo tilẹ jẹ wi pe ẹgbẹ to n ṣe ijọba lọwọ n'ipinlẹ naa n lo awọn eeyan perete kan lati da omi alafia ẹgbẹ oṣelu naa ru sibẹ́ ko ni sewu loko.
Bakan naa lo ni ti igbimọ ẹgbẹ naa si ti gba gbogbo ọna lati pẹtu si irufẹ awọn ẹniyan bẹẹ lọkan, ṣugbọn wọn kọ eti ikun.
Honorebu ni eyi ko seyin pe wọn gbe iṣẹ fun wọn lati ita ni wi pe ki wọn lọ da omi alaafia ẹgbẹ oṣelu PDP ru.
Kini o tun sele pelu Akin Ogunbiyi bayii?
Omo bibi Ile Ogbo ni ipinle Osun ni Akin Ogunbiyi.
Onisowo to di oloselu si ni pelu.
Iroyin kan n so pe nitori ewu ikọ̀lu si awon ero to wa lẹ́yin rẹ̀ lo se jawọ́ ninu idije naa.
BBC Yoruba yoo maa mu gbogbo bo ba se n lọ wa fun un yin,

Oríṣun àwòrán, Others
Kini o kọ́kọ́ seleẹ̀ ninu egbẹ́ Oselu PDP?
Leyin ti Kwankwaso kede pe oun le fi egbẹ́ oselu PDP sile ni Shehu Sagagu rọ̀ Saraki pe ko da si ọ̀rọ̀ Kwankwaso
Bá wa pàrọwà sí Kwankwaso kó má fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀- Alága PDP Kano bẹ Saraki lọ́wẹ̀
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ìpínlẹ̀ Kano, Shehu Sagagu ti pàrọwà sí gbogbo àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú náà láti jíròrò pẹ̀lú gómìnà ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ rí, Rabiu Kwankwaso láti má fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.
Sagagu ni bí Kwankwaso bá fi lè fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ pẹ̀lú ipa rẹ̀ nínú ẹgbẹ́, àdánù ńlá ni yóò jẹ́ fún PDP lásìkò yìí.
- Kíni àjọ ECOWAS ilẹ̀ Adúláwọ̀ ń sọ báyìí lórí ìjà Russia àti Ukraine?
- UEFA gba àǹfàní ìgbàlejò àsekágbá ìdíje Champions League kúrò lọ́wọ́ Russia
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ẹ sọ́ra fún wíwá owó òjijì ẹ̀yin ọ̀dọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ kìí dára- Alake Egba
Alága PDP Kano sọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ikọ̀ olùpolongo ètò ìdìbò ipò Ààrẹ fún Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà tẹ́lẹ̀ rí, Bukola Saraki ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Kano.
Adárí ikọ̀ olùpolongo náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Iyorwuese Hagber ló kó àwọn ènìyàn rẹ̀ sòdí lọ sí ìpínlẹ̀ Kano.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò ṣe dada fún àwọn ọmọ Nàìjíríà
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Jigawa, lọ́jọ́ Ẹtì, Hagber ní nǹkan kò ṣẹnu rere fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ ìṣèjọba ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC).
- Óṣe! Onífàyàwọ́ epo bẹntiróòlù kan àti ìyàwó rẹ̀ jóná mọ́lé , wọ́n fi ọmọ osù mkrin sílẹ̀ sáyé
- Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin
- Wo àwọn asọ ìgbèyàwó àràmọ́ndà, kóo fojú lóúnjẹ òpin ọ̀sẹ̀
- Ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà - Tinubu
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Ìdí tí mo ṣe fẹ́ yọ ayédèrú ìdí ńlá tí mo ní- Sophie
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé
Ó ní làásìgbò tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lásìkò ètò ìdìbò odún 2015 ló ṣokùnfà tí ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe ríbi gba àkóso Nàìjáríà lọ́wọ́ àwọn.
Bákan náà ló ní àwọn ti ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ àwọn padà tí àwọn yóò sì gba agbára lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC padà lọ́dún tó ń bọ̀.
- Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin
- Ohun ìṣeré abánilòpọ̀ há sójú ara mi, mo kú tán - Obìnrin ológun kan
- Wo àwòrán bí Ukraine ṣe rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìkọlù Russia àti bó ṣe rí báyìí
- Ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà - Tinubu
- Ẹ sọ́ra fún wíwá owó òjijì ẹ̀yin ọ̀dọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ kìí dára- Alake Egba
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé

















