Osun PDP: Ewẹ́ ètò ìdìbò sì ń lọ lọ́wọ́ ní Osogbo níbí ti èrò Adeleke pọ̀ sí jú

Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ni wọn kede gẹgẹ bi i ọmọ oye ni igun ikeji ti eto idibo abẹnu PDP ti waye nipinlẹ Ọṣun.
Babayẹmi jawe olubori pẹlu onka 1,781.
Bayii si ni onka awọn oludije to ku ṣe lọ:
Dr Akin Ogunbiyi; 23
Sanya Omirin; 16
Fatai Akinbade; 28
Dele Adeleke; 32.

Họnorebu Adelani Ajanaku ti o kede abajade ibo naa fi idi rẹ mulẹ pe awọn oludibo 1,973 lo fi orukọ silẹ, ibo 27 ni wọn wọgile nigba ti akojọpọ ibo ti wọn di jẹ 1,880.
Abisoye Musibao ti o ṣoju ajọ eleto idibo nibi ipejọpọ naa lo buwọlu abajade onka ibo.
- Timothy Adegoke: Raheem Adedoyin ní káwọn òṣìṣẹ́ Hòtẹ́ẹ̀lì òun fi Bíbélì búra pé wọ́n ò ní tú àṣírí
- Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí Sunday Igboho gbé, tó fi di ọ̀tá ìjọba
- Ademola Adeleke ti dìbò, wo bó ṣe ń lọ ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP Osun ti yapa láti yan ọmọ oyè
- Ẹ má bẹrù láti wọ ọkọ̀ BRT wa, kò séwu - Gómìnà Sanwo-Olu
Kini o n sele bayii ni igun kinni?
Ẹwẹ, eto idibo ṣi n lọ lọwọ ni papa iṣere ilu Oṣogbo nibi ti awọn eeyan Ademọla Adeleke korajọpọ si.
Ninu ọrọ ti Babayẹmi sọ lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi i ọmọ oye ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo apapọ si ipo gomina nipinlẹ Ọṣun lo ti fi ero re han.
O ṣe alaye wi pe igba ọtun ti de nipinlẹ Ọṣun.
O ni gbogbo awọn eniyan to yọwọ ninu ibo naa lati fun oun ni aye ni awọn yoo jọ ṣe ijọba pọ.
Omooba Dotun fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹgbẹ oṣelu naa lo kan lati ṣe ijọba nipinlẹ Ọṣun.

Ademola Adeleke ti dìbò, wo bó ṣe ń lọ ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ́ táwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP Osun ti yapa láti yan ọmọ oyè
Eto idibo abẹnu idibo ẹgbẹ oṣelu PDP ti gberasọ ni ilu Oshogbo.
Idibo naa ti wọn yoo fi yan awọn ti yoo ṣoju gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ n waye lọna meji ọtọọtọ.


Akọroyin wa to wa ilu naa jabọ pe bi ọgọrọ awọn eeyan kan ti wọn wọ ankara iru kan naa ṣe to si ori ila lati ṣe ayẹwo saaju idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party PDP ni gbọngan nla iṣere ilu Oṣogbo, ni ọpọpọlọ awọn eeyan mii naa tun korajọpọ ni iwaju gbọngan nla kan to n bẹ ni Wocdif nilu Oṣogbo.
Ariwo ẹnikan ṣoṣo ti o ku to n fi igagbaga pẹlu Senetọ Ademọla Adeleke, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi si ni wọn n pa.
Ko daju boya wọn yoo dawọ idibo duro lọna kan fun ẹlẹẹkeji ṣugbọn titi di asiko taa n ko iroyin yi jọ, idibo ṣi n lọ lọwọ nibẹ.
Lati gbagede nla iṣere ilu Oṣogbo nibi ti awọn igun Ademọla Adeleke ti korajọpọ lati yan ọmọ oye.
Ademọla Adeleke ti o jẹ oludije, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Họnọrebu Sunday Bisi, Sẹnetọ Francis Fadahunsi ati Ẹniọwọ Bunmi Jẹnyọ wa lara awọn eeyan to wa nikalẹ nibi ipejọpọ naa.

Awọn oludibo ti bẹrẹ sini to si ori ila ijọba ibilẹ wọn, eto idibo naa yoo si bẹrẹ laipẹ.
Bakan naa ni a ri igbimọ kan to joko lori tabili lati ṣe amojuto eto naa, ṣugbọn a ko ti i le fi idi rẹ mulẹ boya igbimọ amuṣẹṣe ni lati ilu Abuja.
A ko ri iru igbimọ bẹẹ lasiko ti a ṣe abẹwo si gbọngan WODCIF nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ mii ti korajọpọ lati gbe sẹyin oludije gẹgẹ bi ọmọ oye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Dọtun Bamidele.
Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹri, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla naa ti darapọ mọ awọn eeyan to wa ni gbọngan WODCIF.

Bakan naa, Oludije gẹgẹ bi i ọmọ oye ninu ẹgbẹ Oṣelu PDP, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi naa ti gunlẹ si gbọngan WODCIF.

To fi mọ ibatan Sẹnetọ Ademola Adeleke, Dele Adeleke ti fi ara han ni gbọngan WODCIF nillu Oṣogbo, nibi ti awọn igun to n tako Ademọla Adeleke ti fẹ yan ọmọ oye ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP.
















