BRT Kidnap Bamise: Sanwo-Olu fàjúro, o ní àwọn tó mọ nípa ikú Bamise yóò fojú winá òfin

Aworan Gomina Sanwo-Olu ati Bamise

Gomina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu ti ba mọlẹbi arabinrin Oluwabamise Ayanwole kẹdun iku rẹ to si ni ijọba yoo ṣa ipa lati ri pe awọn fidi ododo mulẹ lori iku rẹ.

Ninu atẹjade kan loju opo Facebook ni Sanwo-Olu ti fidi ọrọ yi mulẹ to si ni gbogbo awọn to ba lọwọ ninu iku Bamiṣe ni yoo foju wina ofin.

Oluwabamise Ayanwole ni arabinrin ti wọn ri oku rẹ lori afara Carter Bridge nilu Eko lẹyin ọsẹ to kan tawọn mọlẹbi rẹ ke gbajare pe wọn ko mọ ibi to poora si.

Sanwo-Olu ni ijọba ti mu arakunrin to wa ọkọ BRT ti wọn ti ri Bamise laaye kẹyin.

O fi kun pe awọn tun ti paṣẹ fun awọn alaṣẹ ile iṣẹ ọlọkọ ero BRT,Lagos Bus Service Ltd,lati pawọpọ pẹlu awọn to n ṣe iwadii lati tu iṣu de isalẹ koko lori ọrọ yi.

Nibo lọrọ de duro bayii lori iku Bamise?

Akọkọ ni pe ọwọ ti tẹ awakọ BRT to wa ọkọ to gbe Bamise lalẹ ọjọ to ku.

Andrew Nice ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin TVC ti ṣalaye ohun to ṣokunfa iku arabinrin yi.

Ninu fọnran fidio kan to gbode, o ni awọn agbebọn lo wọ Bamise bọlẹ ninu ọkọ ati pe ibẹrubojo lo mu ki oun sa lori afara Carter Bridge.

Ẹlẹẹkeeji ni pe awọn mọlẹbi rẹ ti kesi awọn alaṣẹ lati wa wọrọkọ fi ṣada ki wọn si mu awọn to ba mọ nipa iku Bamise.

Ẹwẹ awọn kan ti n gbero lati ṣe iwọde lọjọ Iṣẹgun lati fhonu han lori iku Bamise Ayanwole.

Iwọde naa gẹgẹ bi awọn iwe pelebe ti a ri kaakiri oju opo ayelujara ṣe sọ, yoo bẹrẹ lati ibudo Gani Fawehinmi ni Ọjọta lọ si ọfisi ijọba ni Alausa.