Sunday Igboho: Wo ìdí tí ọdọ̀ Yorùbá ṣé fẹ́ kí ìlànà Omo Oódua gbajumọ́ Yoruba Agenda lọ́dún 2023 dipo Yoruba Nation

Aworan Igboho ati awọn agbaagba Yoruba

Awọn olori ikọ ọdọ ilẹ Yoruba labẹ asia igbimọ Apapọ Ọdọ Yoruba Lagbaye, Yoruba Council of Youth Worldwide sọ pe awọn yoo lu ijọba apapọ Naijiria lọgọ ẹnu lọna ati yanju ọrọ ni tubi n nubi pẹlu awọn ẹgbẹ ajijagbara.

Ẹgbẹ naa naa ni afojusun awọn ni ki ijiroro to peye waye laarin ijọba Naijiria, Ilana Omo Oodua ati awọn ẹgbẹ ajijagbara mii ni Naijiria.

Lasiko ti wọn n ba ọmọ Yoruba dawọ idunnu itusilẹ Sunday Igboho latimọle ni ikọ yi fi ọrọ ọhun sita ninu atẹjade gba tọwọ aarẹ Oladotun Hassan.

Hassan sọ pe igbagbọ awọn ọdọ ni pe ki wọn dari igbiyanju kuro lori idasilẹ Yoruba Nation bọ sori ọna ati mu itẹsiwaju ba ijọba awarawa Naijiria.

''Ipe fun Yoruba Agenda ni 2023 ti yoo lanfaani fawọn eeyan wa, ti a o si ribi fẹnuko nibi ijiroro nkan taa ba fẹ lo yẹ ki a la kalẹ''

O tẹsiwaju pe ohun to yẹ kawọn ọmọ Naijiria ṣe ni ki wọn wa ọna to munadoko lati jiroro lori iwe ofin ilẹ yi tuntun eleyi ti ''yoo mu ọna iṣejọba awarawa tuntun mii wa''

Oladotun Hassan to gboṣuba kaare fun awọn agbaagba Yoruba ati ijọba orileede Benin sọ pe ẹgbẹ awọn naa kopa ribiribi ninu itusilẹ Igboho.

Ọrọ ti Oladotun fi kun alaye rẹ bakan naa ni pe o yẹ kawọn eeyan pawọpọ lati koju ipenija aabo, iṣẹ ohun oṣi, airiṣẹ ati awọn ipenija mii to ti doju ẹ bayi ni Naijiria.

Lafikun o ni,bi wọn ba ṣe n koju awọn ipenija yi ki Naijiria ma baa daru, bẹẹ lo yẹ ki wọn san owo gba ma binu fun Igboho lori dukia rẹ to bajẹ ati fawọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn.

Awọn wo ni Yoruba Council of Youths Worldwide

Lẹnu igba ti ariwo Yoruba Nation bẹrẹ yi la ti bẹrẹ si ni gbọ orukọ awọn ikọ orisirisi to n ṣoju awọn ẹya Yoruba.

Ninu wọn ni igun Yoruba Council of Youths Worldwide yi wa ti awọn naa si ti n ba wọn pe fun itusilẹ Sunday Igboho.

Afihan idanimọ ẹgbẹ ọdọ Yoruba ati Sunday Igboho

Gẹgẹ bi awọn ikọ miran to n ṣoju ọdọ lẹkunjẹkun Naijiria bi Ohanaeze Ndigbo Youth Worldwide, Arewa Consultative Yoputh Forum ni ikọ yi jẹ.

Bawọn agbaagba Yoruba ba n sọ ohun ti wọn fẹ, igun awọn ọdọ yi naa a maa saba sọ ti wọn naa botilẹ jẹ pe a ko mọ boya ibi kanna ni wọn kọju si lori ọrọ.

Loju opo Facebook, a ri pe ikọ yi ni ẹka awọn ọmọ ẹgbẹ ni ipinlẹ Ekiti, Oyo, Ogun ati ijọba ibilẹ Ado odo/ota.

Pẹlu atẹjade ti awọn ọdọ yi gbe jade, o fẹ ṣebi ẹni pe wọn yapa kuro loju ọna awọn ẹgbẹ bi Ilana Omo Oodua to ni afi ki ijọba jẹ ki iẹya Naijiria ya sọtọ ni.