Osinbajo ni yóò máa tukọ̀ ìjọba ní báyìí tí mò ń lọ gbàtọ́jú nílùú London - Buhari

Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Presidency

Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ni yoo maa tukọ Naijiria fun ọsẹ meji gbako ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo lo niluu London nibi ti yoo ti lọ ri awọn dokita rẹ.

Buhari lo kede ọrọ naa lọjọ Aiku nigba ti n ba awọn akọroyin sọrọ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe, nibi ti baluu rẹ ti gbera niluu Abuja.

O ni Osinbajo nikan kọ ni yoo maa tukọ orilẹ-ede nigba ti oun ko si nile nitori aẉọn eeyan mii yoo wa pẹlu rẹ lati tukọ ijọba naa.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Buhari sọ pe "Mi o le sọ pe emi nikan ni mo n ṣiṣẹ Aarẹ, ọpọ eeyan lo wa ninu ijọba."

"Igbakeji Aarẹ wa nibẹ, gẹgẹ bii ofin ṣe sọ, oun ni yoo m,aa ṣe ijọba ti mi o ba si nile"

Ṣaaju ni Buhari ti kọkọ gbero lati lọ si London lati orilẹ-ede Nairobi, nibi to ti lọ ṣe ipade ajọ UN lori ọrọ ayika, aadọta iru rẹ, amọ ṣadede lo apada wale lọjọ Ẹti."

Àkọlé fídíò, Kiki Osinbajo: T;o bá yá owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, máa gbìyànjú láti da padà

Buhari tun sọrọ lori ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu APC ti yoo waye laipẹ, o ni ọkan oun balẹ pe ipade naa yoo lọ wọọrọwọ.

Ki ni awọn araalu n sọ nipa bi Aarẹ ṣe n gba itọju ni London?

Kii ṣe igba akọkọ ree ti Aare Buhari yoo lọ gba itọju niluu London.

Ọpọ awọn Naijiria lo si ti bẹrẹ si n fi erongaba wọn lede nipa irinajo naa, paapaa lasiko yii ti iya epo bẹntiro n jẹ awọn araalu.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Ninu atẹjade kan, ẹgbẹ oṣelu PDP ni ohun ti Buhari ṣe ku diẹ kaato nitori awọn ọmọ Naijiria ko ri epo ra sinu ọkọ wọn, ọrọ ASUU ko tii yanju, Aarẹ si gbojugboya lati lọ ri awọn dokita rẹ niluu okeere, bẹẹ ilu Dubai ni iyawo rẹ, Aisha fi n ṣebugbe.

Awọn ọmọ Naijiria mii tun sọ pe Aarẹ ko ni ojuti kankan, bii bẹẹ kọ, ni ṣe lo yẹ ko kọ ile iwosan to dangajia si Naijiria dipo bo ṣe n ko owo ilu lọ silẹ mii.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà