2023 Presidential Election: Ajulo ní ó ti ń rúgbó bọ̀ láàrin Tinubu àti Osinbajo, àwọn àgbà Yorùbá kò gbọdọ̀ wòran

Yemi Osinbajo ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ nitori bi aye ba toju agba bajẹ, a jẹ pe aimọ iwa hu wọn ni.

Eyi lo mu ki agbà ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò kan, Dókítà Kayode Ajulo, ti ké sí awọn agbaagba nilẹ Yoruba lati dide yanju aawọ si ọrọ oselu lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.

Ajulo wa ke si Ààrẹ àná lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo, Ọọ̀ni ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyeye Ogunwusi ati Awujalẹ ti Ìjẹ̀bú, Ọba Sikiru Adetona.

Bakan naa lo tun n ke si Alake ti Ẹgba Ọba Adedotun Aremu Gbadebo, Aare Ona Kakanfo fun ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ati alagba Ayo Adebanjo ti Afenifere.

Kayode Ajulo tun nahun ke si àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá mìíràn sugba ara wọn fi wa ojutu si aawọ oselu naa.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Ki lo de ti Ajulo fi n ke sawọn agbaagba Yoruba?

Pataki ohun ti Ajulo n pe awọn agbaagba yii fun ni láti tètè paná rògbòdìyàn tó fẹ́ máa ṣúyọ lágbo òṣèlú láàárín Adarí àpapọ̀ fẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu àti igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí, Yemi Osinbajo.

Ajulo ní àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Yorùbá gbọ́dọ̀ pe àpérò ńlá níbi tí gbogbo àwọn adarí ilẹ̀ Yorùbá, tó fi mọ́ àwọn gómìnà tó wà lórí ipò àti àwọn tó ti fi ipò sílẹ̀.

O ni ti wọn ko ba pe ipade ajọ nla to nironu nilẹ Yoruba lori eto oselu, afaimọ kí ẹkùn Yorùbá mase rí ọwọ́ mú níbi ètò ìdìbò gbogbogboò ọdún 2023.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Ajulo fi síta ló ti wòye awuyewuye tó ń wáyé láàárín alátìlẹyìn Tinubu àti Osinbajo léyìí tó ní ó le ṣe ìdíwọ́ fún kí ilẹ̀ Yorùbá pèsè Ààrẹ lọ́dún 2023.

"Yóò jẹ́ àdánù ńlá kí ẹkùn Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn pàdánù ipò láti mú àtúntò bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà."

"Ohun tí ó fóju hàn ni pé kò sí ááwọ̀ láàárín Tinubu àti Osinbajo ṣùgbọ́n àwọn alátìlẹyìn wọn ti ń ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn."

Amin iyasọtọ kan

Adarí àgbà fún àjọ àgùnbánirọ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NYSC), ọ̀gágun Shuaibu Ibrahim ti sọ lọ́jọ́ Ẹtì pé ipa àwọn àgùnbánirọ̀ sí ìṣọ̀kan àti ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè yìí kò ṣé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá.

Agunbaniro

Oríṣun àwòrán, @NYSC

Shuaibu ní Ìpínlẹ̀ Kaduna sọ pé láìsí àwọn àgùnbánirọ̀ ìkúrẹtẹ̀ kò bá ti bá ètò ẹ̀kọ́ àti ìlera.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ìtẹ̀wé àjọ náà, tó sì ké pe awon ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣàtìlẹyìn fún àjọ náà kí ìdí tí wọ́n fi ṣe ìdásílẹ rẹ̀ ba a lè jẹ́ àmúṣe.

Bákan náà lọ pé fún àtìlẹyìn NYSC Trust Fund lójúnà à ti lè máa fún àwọn àgùnbánirọ̀ ní owó tí wọ́n yóò máa fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò ní kété tí wọ́n bá ti parí sísin ilẹ̀ baba wọn tán.

Àkọlé fídíò, Wo ọmọ tó kọ̀ láti sin òkú ìyá rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ìdí tó fi kọ̀ bẹ́ẹ̀

Awọn iṣẹ wo ni Agunbanirọ n ṣe ni Naijiria bayii?

Shuahibu tẹ̀síwájú pé onírúurú okoòwò ni àjọ NYSC ti dágbálé bíi ilé iṣẹ́ aṣọ, ilé iṣẹ́ omi àti ilé ìtẹ̀wé, tó sì ní gbogbo owó tí àwọn bá ń rí níbẹ̀ ni wọn yóò máa kó sí àpò ijoba.

Shuahibu fi kun un pé èròńgbà àwọn ni láti ní ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan ni gbogbo ẹkùn mẹ́fà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lójúnà à ti rí pé àwọn àgùnbánirọ̀ ń kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ lásìkò tí wọ́n bá ń sin ilẹ̀ baba wọn.