Michael Jackson: EFCC ní ọ̀pọ̀ apẹ òògùn ìbílẹ̀ ní wọn ká mọ́ afurasí oníjìbìtì náà lọ́wọ́

Michael Jackson to gbe igba oogun lọwọ

Oríṣun àwòrán, EFCC/Instagram

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (EFCC), ti nawọ́ gán arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michael Jackson fún ẹ̀sùn lílu jìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Afurasí ọ̀hún ni wọ́n fi òfin gbé lẹ́yìn tí olobó kan ta wọ́n pé afurasí náà ń lọ́wọ́ nínú jìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Àjọ EFCC ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù ni Micheal Jackson tí gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn látàrí bí ó ṣe ń pé ara rẹ̀ ní Ella, obìnrin tó pa ara rẹ̀ dà sí abo.

Ìròyìn ní afurasí náà ló ń pe ara rẹ̀ ni DJ tó sì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ògùn lọ́wọ́.

Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota 4-runner kan, Honda Accord kan, àwọn ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà alágbèká àti fóònù kan ni wọ́n rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀.

Agbenusọ àjọ EFCC, Wilson Uwajuren ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn yóò wọ lọ sí ilé ẹjọ́.

Michael Jackson

Oríṣun àwòrán, EFCC