Ekiti PDP Primary: Segun Oni ní ejò lọ́wọ́ nínú bí Udom ṣe gba Fayose láàyè láti jókòó sí àgọ́ ìdìbò

Awọn agbaagba ẹgbẹ PDP

Ikọ̀ ìpolongo ètò ìdìbò abẹ́nú Segun Oni ti kọ èsì ìdìbò tó gbé Bisi Kolawole wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP níbi ètò ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀ lọ́nà ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí adarí àgbà ikọ̀ náà, Yemi Arokodare fi léde ní ọjọ́'bọ̀, ní Ado-Ekiti fẹ̀sùn kàn pé àwọn tó darí ètò ìdìbò náà kò jẹ́ kí àwọn ènìyàn àwọn dìbò.

Gómìnà Emmanuel Udom ti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom tó darí ètò ìdìbò abẹ́nú náà kéde Bisi Kolawole gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jáwé olúborí bí ó ṣe ní ìbò 671, tí Segun Oni tó úmọ sì ní ìbò 330.

Arokodare ní wọ́n ti ṣèrú ìwé orúkọ bí ọ̀pọ̀ orúkọ àwọn ọmọ ikọ̀ ti wọn kò ṣe sí níbẹ̀.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn méjìlélọ́gbọ̀n nínú àwọn ènìyàn àwọn tí orúkọ wọn nínú ìwé tí wọn sì ṣe àyẹ̀wò fùn ún ni wọn kò jẹ́ kí wọ́n ó dìbò.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Arokodare tún fẹ̀sùn kàn pé Udom ní òun yóò fi ọlọ́pàá gbé àwọn ènìyàn wọn, tí wọn bá wọ inú gbọ̀ngán tí ètò ìdìbò náà ti wáyé.

Ó tẹ̀síwájú pé, Udom gba Ayo Fayose láàyè láti jòkó sínú ibi tí wọ́n ti dìbò lẹ́yìn tó dìbò tán, ìwà tó ní ó lòdì sí òfin tí Udom ti ṣaájú kéde.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní gbogbo àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ Fayose ni Udom gbà láàyè láti jòkó sínú gbọ̀ngán náà láti dúnkokò mọ́ àwọn olùdìbò yòókù.

Arokodare gúnlẹ̀ pé ètò ìdìbò náà ní ọwọ́ kan nínú nítorí Udom wá fi ṣe ẹsan fún Fayose tó darí ètò ìdìbò abẹ́nú tó gbé e wọlé ní Akwa Ibom.

Ó ní ìdí nìyìí tí àwọn fi ń ṣàgbéyẹ̀wò ètò àwọn adarí ẹgbẹ́ lókè nípa ṣíṣe àmójútó ẹgbẹ́ kí wọ́n le jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ 18, oṣù kẹfà, ọdún 2022.

Amin iyasọtọ kan

Bisi Kolawole, àyànfẹ Fayose ni olùdíje PDP fún ipò gómìnà l'Ekiti

Aworan Bisi Kolawole

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bisi Kolawole For Ekiti 2022

Ọtunba Ọlabisi Kọlawọle ti bori gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti.

Ọtunba Bisi Kọlawọle ni ibo ọrinlelẹgbẹta o din mẹsan, 671 lati lewaju gbogbo awọn oludije to dije fun asia ẹgbẹ oselu naa.

Gomina Emmanuel Udom to kede esi idibo naa ṣalaye pe ẹgbẹrun kan o le igba ati mẹjọ 1208 asoju lo kogoja lati dibo.

Pẹlu bi esi naa ṣe ri bayii, oun ni yoo maa ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ti yoo maa waye loṣu kẹfa ọdun 2022.

Eto ibo awọn aṣoju lati yan oludije ẹgbẹ oselu naa fun idibo gomina l'Ekiti waye lọjọ Iṣẹgun, laisi wahala tabi jagidijagan kankan rara.

Aworan Bisi Kolawole
Aworan Segun Oni ati Bisi Kolawole

Nigba to n sọrọ, Ọtunba Bisi Kọlawọle dupẹ pupọ lọwọ awọn oludije yooku to si fi idaniloju rẹ han pe ko si ikunsinu kankan lori abajade esi naa pẹlu awọn oludije yooku.

Ṣaaju ni Olusẹgun Oni to ṣe ipo keji ti kọkọ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe bi adari igbimọ eto idibo naa, gomina Emmanuel Udom ti Akwa Ibom ti ṣe gbiyanju to awọn eeyan kan ninu ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti ko jẹ ki ọrọ naa yanju bi oun ṣe fẹ.

Ṣaaju si ni okan lara awọn oludije naa, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi naa ti fariga to si ju iwe silẹ pe oun ko ṣe mọ lẹyin ti o fi ẹsun kan igbimọ iṣakoso ibo naa pe ko ṣe deede pẹlu oun atawọn alatilẹyin oun.

Amin iyasọtọ kan

Awọn oludije yooku ati ibo ti wọn ni niwonyi :

Kayode Adaramodu =10 votes

Oluṣọla Kolapo Eleka = 93 votes

Adewale Aribisala = 56 votes

Segun Oni = 330 votes

Bisi Kọlawọle =671

Oluyinka Akerele

Oluwatoyin Debora Alọ =1

Olukemi olumide= 1

Abiọdun Olujimi =2

Ayodeji Kazeem 6

Amin iyasọtọ kan

Ta ni Bisi Kolawole, ayanfẹ Oshokomọlẹ to n gbe asia PDP fun ipo gomina ni Ekiti?

Ayanfẹ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose ni Bisi Kolawole jẹ.

Ṣaaju ko to dije dupo oludije ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP Kolawole to wa lati ẹkun idibo Efon Alaaye ti ṣe aṣofin nile aṣojusofin Naijiria ri.

Laarin ọdun 2007 si 2011 lo di ipo yi mu to si tun ti ṣe Kọmiṣana ri labẹ ijọba Fayose laarin dun 2015 si 2018.

Ninu awọn korikosun Gomina Ayodele Fayose lo wa to si tun jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ekiti.

Aworan Bisi Kolawole

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bisi Kolawole for Ekiti 2022

Bakan naa ni Bisi Kolawole ti jẹ alakoso eto ipolongo fawọn oludije meji nigba kan ri, iyẹn Dayo Adeyeye ati Olusola Eleka.

Bisi Kolawole tun ti jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti ri tos i ṣe pe o fi ipo naa silẹ loṣu Kẹsan ọdun 2021 ni ko ba lee dije oludije ipo Gomina.

Bayi ti wọn ti yan lati dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ohun to ku bayi ni lati ri boya yoo jawe olubori gẹgẹ bi oludije Fayose.

Aworan Bisi Kolawole

Oríṣun àwòrán, fACEBOOK/Bisi Kolawole For Ekiti 2022

Olusola Elẹka ti Fayose fa kalẹ ninu idibo ọdun 2018 kuna lati de ipo Gomina lẹyin ifidirẹmi lọwọ Gomina to wa nibẹ bayi Kayode Fayemi.

Fayemi ko ni kopa ninu idibo ọdun yi taa si n reti ẹni ti ẹgbẹ APC yoo fa kalẹ ninu idibo abẹnu ti wọn naa to yẹ ko waye lonii.