EndSARS Protest: Samuel Ogundeji gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lẹ́yìn tí SARS fọ́ ojú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Samuel Ogundeji, ti oju rẹ fọ lẹyin ti awọn agbofinro SARS lu nilu bara ti gba ẹbun ẹkọ ọfẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Oyo.
SARS fiya jẹ ọdọkunrin naa lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o ji apo ilewọ oṣiṣẹ ile ifowopamọsi kan.
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lo kede ẹbun ọfẹ naa lasiko to n tẹwọgba abọ iwadii igbimọ ti ijọba rẹ gbe kalẹ lẹyin iwọde EndSARS ni Agodi, Ibadan.
- Ilé aṣòfin n rẹkẹ, Boris Johnson takú, tá ní yóò bóri lórí awuyewuye ''party'' ọjọ́ ìbí?
- Michael Jackson, ọkùnrin tó sọ ara rẹ̀ di obìnrin kó sí pańpẹ́ EFCC
- Erin tẹ arìnrìn-àjò pá níbi tó ti ń ṣẹ̀yọ́
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
- Ìdìbò láti yan olùdíje APC fún ipò gómìnà ṣì ń tẹ̀síwájú - Ìgbìmọ̀ APC
- Pásítọ̀ mi bá àbúrò mi ṣe àṣemáṣe, gba mílíọ́nù àkọ́kọ́ tí mo pa bíi òṣèré tíátà, ó tún já ojú òpó ayélujára mi gbà - Toyo baby
- Bisi Kolawole, àyànfẹ Fayose ni olùdíje PDP fún ipò gómìnà l’Ekiti
- Ìyè èèyàn mélòó ní wọ́n dáná sun pẹlú Kábíyèsí Agodo?ọlọ́pàá tú àṣírí
Makinde sọ pe gbogbo akitiyan igbimọ oluwadii EndSARS naa ko lọ lasan, ati pe ijọba oun yoo gbiyanju lati tẹle awọn aba to wa ninu abọ iwadii wọn.
Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin abẹle Daily Trust ti kọkọ jabọ pe ijọba ipinlẹ Oyo ti san lara owo ile ẹkọ Ogundeji, to fi mọ ile to n gbe ati awọn aṣọ to n wọ.
A ko gbe igbimọ iwadii EndSARS kalẹ lati da ẹnikẹni lẹbi:
Makinde sọ fun igbimọ naa nibi ipade ọhun pe "Inu mi dun pe ẹ ṣe ohun ti mi o lero nipa sisan lara owo ile ẹkọ rẹ, ẹ jọmi loju gigi gan ni."
"Idi ti a ṣe gbe igbimọ yii kalẹ ree, kii ṣe lati da ẹnikẹni lẹbi, amọ lati yanju awọn iṣoro to wa nilẹ."
"Awa gẹgẹ bii ijọba, a oo ri pe ọmọ yii gba ẹbun ẹkọ ọfẹ lati ọdọ wa, a oo san owo ile ẹkọ rẹ, a oo si tun maa fun owo perete titi ti yoo fi pari ile ọkọ rẹ."
Makinde fi kun pe ijọba oun yoo ri daju pe awọn mọlẹbi gbogbo ọlọpaa to ba iwọde EndSARS naa lọ yoo ri idajọ ododo gba.
O ni "Awọn ọlọpaa naa ku lasiko iṣẹlẹ ọhun, eeyan ni awọn naa, ọmọ Naijiria si ni wọn... A oo wa nnkan ṣe fun awọn mọlẹbi wọn."
Bi igbimọ oluwadii naa ṣe waye:
Lẹyin rogbodiyan to waye nitori iwọde EndSARS ni awọn gomina kaakiri Naijiria gbe igbimọ kalẹ lati fi oju ṣunukun wo ọrọ naa, paapaa awọn ẹsun ti awọn araalu fi kan ọlọpaa.
Ni ipinlẹ Oyo, Adajọ Badejoko Adeniji lo tukọ igbimọ naa, igbimọ ọhun si gba iwe ẹbẹ ti iye rẹ ko din ni aadọjọ kaakiri ipinlẹ Oyo.
Igbimọ ọhun naa wọgile iwe ẹbẹ ọgbọn ninu aadọjọ ti wọn gba.
Adajọ Adeniji to tukọ igbimọ ọhun sọ pe awọn to kọwe ẹbẹ si igbimọ naa yoo ri idajọ ododo gba ni bayii ti awọn pari iwadii wọn.


















