Elephant kills Tourist in Uganda: Àlàyé rèé lórí bí erin ṣe tẹ arìnrìnàjò afẹ́ kan pa

Awọn ọmọ erin ati iya wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Adura ti ọpọ eeyan ma n se ni pe ki Ọba oke mase jẹ ka rin arinfẹsẹsi, ka ma bọ sọwọ ohun ti yoo jẹ wa.

Amọ adura yii ko gba fun ọkunrin Arìnrìn-àjò kan ni ọgba àwọn ẹranko to wa ni orílẹ̀ èdè Uganda.

Idi ni pe se ni Erin tẹ paa nigba to bọ́lẹ̀ nínú ọkọ tó ń gbé rin ìrìn àjò.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Bawo ni isẹlẹ naa se waye:

Olóògbé náà, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Saudi, ló ń gba ọgbà Murchison Falls lọ sí ìlú Arua kó tó sọ̀kalẹ̀ nínú ọkọ láti tọ̀.

Níbi tó ti ń ṣẹ̀yọ̀ọ́ yìí ni àwọn erin yà bò ó, tí kò sì rí bi sá wọnú ọkọ̀ nítorí ó ti rìn jìnà síbi tí ọkọ̀ wà.

Àwọn alámòjútó ọgbà náà fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun náà múlẹ̀, tí wọ́n sì ní ìwádìí ń lọ lọ́wọ́.

Wọ́n fi kun pé àwọn ń gbìyànjú láti rí dájú pé irú rẹ̀ kò wáyé mọ́.

Irúfẹ́ ìkọlù báyìí látọwọ́ àwọn ẹranko ló ti máa ń wáyé ní àwọn ọgbà ẹranko ni Uganda.