Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Ilu kan tun ree nilẹ Yoruba, ilu Ìwóró, nibi ti omi kan wa ti wọn n pe ni Omi-Dájì eyi ti wọn lo n se iwosan agbayanu.

BBC Yoruba tẹkọ leti lọ silu Iworo lagbegbe Badagry lati foju se mẹrin omi onisẹ iyanu yii ati lati fidi ootọ mulẹ nipa awọn isẹ iwosan lorisirisi ti wọn lo n se.

Bawo ni wọn se tẹ ilu Ìwóró dó?

Ninu iwadi BBC Yoruba, a gbọ̀ lati ẹnu Osi Ọba ilu Ìwóró, Alhaji Ashade Azeez pe Ajagun lo tẹ ilu Ìwóró dó pẹ̀lu àwọn jagun jagun mẹrin miran, ilu Ile Ife si ni gbogbo wọn ti wa.

Orukọ awọn jagun jagun mẹrin naa ni Aláruwẹ, Ọ̀dọ̀fin. Ògún-Àjẹgọ̀ àti Ìsẹ́kì, ti wọn si tọ Ajagun wa lẹyin to ti tẹ ilu naa do tan.

O ni awọn eeyan yii pẹl iyawo wọn ni wọn n wa omi ti wọn yoo lo kiri, titi ti wọn fi de ibudo ti omi Dájì wa loni yii.

Ki ni itan to rọ mọ omi Dájì, bawo lo se bẹrẹ?

Nigba to n salaye bi omi Daji se bẹrẹ, Alhaji Azeez Ashade ni omi naa ko ni orisun tabi ibi to ti sẹ wa rara.

O fikun pe funra ara omi naa lo bẹrẹ si sun jade lai ni ibi to ti bẹrẹ tabi pari si.

Ashade ni ibi ti iyawo Aláruwẹ̀ duro si lasiko ti wọn n wa omi kiri kan dede dá jìn sinu, ti omi kan si bẹrẹ si ni tu jade sita puu puu.

Idi si ree ti wọn se n pe omi naa ni Omi-Dájì titi di oni.

Ọpọ iwosan to wa ninu mimu ati lilo omi Daji:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oníwòóró ti ìlú Ìwóró, Ọba Idris Oladele Kosoko salaye pe ọpọ iwosan to lagbara ni omi Daji maa n se.

Lara awọn iwosan naa ni wiwo inu rirun, ori fifọ ati ọpọ aisan ati arun lorisirisis.

Bakan naa ni Ọba Kosoko fikun pe Omi Daji tun maa n fun awọn agan ni ọmọ, ti onitọun ba ti le maa mu omi naa loore koore.

O wa fi ti obinrin kan to ni oyun Ìju se akawe. O ni lẹyin ti obinrin naa se isẹ abẹ tan, to yọ iju inu rẹ ni ko ba ri ọmọ bi.

Amọ nigba to bẹr si mu omi Daji, se lo fi inu se oyun, to si fi ẹyin rẹ gbe ọmọ rẹ pọn.

Awọn ohun aramọnda miran ti omi Daji maa n se:

Ọba Kosoko tun fikun pe omi Daji yii ni wọn maa n fi sure fun ọba tuntun to ba jẹ nilu naa, ko si si ọba ti yoo jẹ, ti ko ni de idi omi Daji.

Tun wẹ, Ko si ẹnikẹni to gbọdọ pa awọn ẹja to wa ninu omi Daji, bi eeyan kan ba si fẹ pa ẹja naa, se ni awọn Orò yoo maa ke tantan.

O fikun pe asiko ti wọn ba fẹ ko ẹja naa, wọn yoo gbe Oro sita, ti yoo maa ke, bẹẹ ni wọn ko ni se ẹja ti wọn ba ko nibẹ tabi ki ẹnikẹni jẹ.

Amọ Ọba ati awọn agbaagba ilu nikan ni wọn mọ bi wọn se n se ẹja naa.

Oriade naa tun fidi rẹ mulẹ pe Omi Daji kii gbẹ boya nigba ojo ni tabi nigba ẹẹrun.

A fẹ ki ibudo Omi Daji di ibudo irinajo afẹ - Oniworo

Oniworo tilu Iworo wa sisọ loju rẹ pe awọn n fẹ ki wọn sọ ibudo Omi Daji yii di ibudo Igbafẹ ti awọn arinrinajo afẹ yoo maa ya wa wo.

O ni ara aayan awọn lati jẹ ki erongba naa wa si imusẹ ni bi awọn se satunse ibudo omi naa, eyi to mu ko wu oju ri pupọ fun awọn arinrinajo afẹ.

Kabiyesi fikun pe awọn yoo tun gba ẹnikan bii ẹsọ si ojubọ naa, ti yoo maa mu awọn arinrinajo afẹ kiri ibudo naa, ti yoo si tun maa sọ itan to rọ mọ omi naa fun wọn.