Juliana Olayode: Kí ni àṣírí "Toyo Baby" tó wà lọ́wọ́ Pásítọ̀ rẹ̀ tí ariwo fi ta?

Juliana Olayode

Oríṣun àwòrán, Juliana Olayode/Timi Adigun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Họwuhọwu to n waye laarin oṣerebinrin Juliana Olayode, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si "Toyo baby" ninu fiimu Jenifa's Diary ati pasitọ rẹ ti gbọna mii yọ.

Ija awọn mejeji, ti wọn ti fi igba kan jẹ baba ati ọmọ ninu igbagbọ ri n da oniruru ariyanjiyan silẹ laarin awọn ololufẹ awọn mejeji lori ayelujara.

Bi Juliana ṣe n sọrọ lori ikanni Instagram rẹ naa ni pasitọ ọhun n fesi pada loju opo tirẹ.

Ki lo ṣẹlẹ laarin Juliana ati Pasitọ rẹ?

Ṣaaju ni Juliana ti kọkọ fẹsun kan Pasitọ rẹ ọhun, iyẹn Timilehin Adigun, to jẹ oludasilẹ ijọ Mine Teens Ministry, pe o ja oju opo Facebook oun gba.

Juliana tun sọ pe Pasitọ ọhun kọ lati jọwọ kọkọrọ oju opo naa fun oun.

Ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ, oṣerebinrin ọhun ṣalaye pe Pasitọ naa, to ti figba kan jẹ alakoso oun ri n gbiyanju lati fi ọwọ ọla gba oun loju bo tilẹ jẹ pe oun ti fun ni ọpọlọpọ owo sẹyin.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

O ni "Mo lọ Timilehin ninu ṣọọsi rẹ pe ko fun mi kọkọrọ si oju opo Facebook mi nitori mi o mọ bi wọn ṣe n lo oju naa, amọ ni ṣe lo ni ki awọn ẹṣọ ṣoọṣi naa le mi jade lẹyin ti mọ la orukọ mọ lori."

"Mo ranti ọjọ kan ti Timilehin fi aworan oun ati iyawo rẹ si oju opo Facebook ọhun nitori pe ọwọ rẹ ni kọkọrọ rẹ wa ati pe mi o mọ bi wọn ṣe n lo oju opo Fabook."

"Lẹyin naa ni Timilehin mọọmọ dawọ iṣẹ Facebook naa duro."

Oṣere naa ni ọrọ ọhun dun oun pupọ, koda ni ṣe lo n wa ẹkun mu.

Lẹyin naa lo ke si awọn ololufẹ rẹ ki wọn ba a bẹ pasitọ Timilehin ko jọwọ kọkọrọ oju Facebook ọhun.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere

Juliana ri mi fin,mo si ti bẹẹ tẹlẹ lori ẹs ti mo sẹẹ amọ ko si kọkọrọ Facebook rẹ lọwọ mi - Pasitọ Timilehin

Nigba ti yoo fesi, Timilehin Adigun sọ pe irọ ni oṣere naa n pa pe oun mọọmọ kọ lati di kọkọrọ oju opo Facebook rẹ mu, ati pe kọkọrọ naa ko si lọwọ oun paapaa.

Ninu fidio to di soju opo tirẹ, o sọ fun oṣere naa pe "Nigba ti mo n ṣe alakoso rẹ, mo n ṣe gẹgẹ bii baba si ọmọ ni, mi o si gba owo kankan lọwọ rẹ."

"Mo ti sọ kọkọrọ awọn oju naa fun ọ nitori ko si nnkankan ti n oo fi kọkọrọ naa ṣe, mo gba ọ nimọran lati lọ wo inu awọn iwe ti o n kọ kọkọrọ naa si."

Pasitọ naa tẹwaju pe o jẹ ohun ibanujẹ fun oun pe Juliana ri oun fin ati pe aṣiri rẹ wa lọwọ oun, amọ oun ko fẹ tu aṣiri naa sita.

O ni "Bi ọmọ ni o jẹ si mi Juliana mi o si lero pe o tọ si ọ lati la orukọ mọ mi lori."

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

"Bii baba ni mo jẹ si ọ nitori emi ni mo tọ ẹ dagba."

"Mo n reti ki o wa bẹmi ki a si pari ija to wa laarin wa tẹlẹ ni amọ o kọ lati ṣe bẹẹ... Aṣiri rẹ wa lọwọ mi, amọ bii baba gidi mi o ni tu aṣiri naa sita."

Ibi ọrọ de duro:

Lẹyin ni fidio Pasitọ naa ni Juliana tun fi fidio mii sita, nibi to ti fẹsun kan pasitọ naa pe ko sọrọ soke ti oun ba ni aṣiri kanka lọwọ rẹ, ati pe Pasitọ ọhun gan lo ni aṣiri si oun lọwọ nitori o ti figba kan ba aburo oun atawọn mẹta mii ni ibalopọ ri, amọ wọn ṣe ọrọ naa ni oku oru.

Ẹwẹ, pasitọ Timilehin ti fesi loju opo Instagram rẹ pada pe oun ko ba aburo Juliana tabi ẹnikẹni ni ibalopọ, oun si ṣetan lati foju bale ẹjọ lori ọrọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi