Ekiti APC Primary: Ìdìbò láti yan olùdíje APC fún ipò gómìnà l'Ekiti ń parí lọ láwọn wọ́ọ̀dù kan

Awọn alatilẹyin awọn oludije gomina ni Ekiti to n se iwọde

Idibo ti pari lawọn wọọdu kan ti awọn miran si ti n mura ati pari tiwọn lawọn Ibudo idibo wọọdu mẹtadinlọgọsan ti eto idibo ati yan oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC ti n waye nipinlẹ Ekiti.

Bi o tilẹ jẹ pe awon oludije mẹfa kede lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Ado Ekiti pe awọn ko lọwọ si eto naa mọ, afi ki awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa wọgile idibo ọhun.

Oludije ti awuyewuye n mi dugbẹdugbẹ lori rẹ, Ọgbẹni Bamiji ni awọn ẹsun ti awọn oludije yooku n gbe dide ṣe ajeji si oun nitoripe oun ko gbọ pe ẹnikẹni ninu wọn tako eto yiyan oludije ẹgbẹ oselu naa.

Amoṣa o ni inu oun dun si bi eto naa ṣe n lọ, gbogbo ikunsinu awọn oludije yoku ni wọn yoo si yanju gẹgẹ bi ọrọ mọlẹbi laarin agbo ẹgbẹ oṣelu naa.

Nibayii awọn onwoye atawọn ọmọ ẹgbẹ ṣi n reti igbesẹ ti awọn ọmọ igbimọ eleto idibo fun idibo naa labẹ alaga gomina ipinlẹ Jigawa yoo gbe lori eto naa.

To n tumọ si pe wọn ko tii le sọ boya alaga ọhun yoo wọgile eto naa gẹgẹ bi awọn oludije mẹfa naa ṣe beere fun ni tabi yoo tẹsiwaju lati kede ẹni to ba jaweolubori gẹgẹ bii oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ wọn.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ìdìbò láti yan olùdíje APC fún ipò gómìnà ṣì ń tẹ̀síwájú - Ìgbìmọ̀ APC

Olu ile ẹgbẹ oselu APC ni Ekiti

Igbimọ to n ṣe aayan ibo lati yan oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti ti kede pe ko si ounyẹ kan ko le yẹ eto naa.

Awọn mefa ninu awọn oludije mẹjọ to n dije ni wọn peju si olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC lati fi ẹhonu han lẹyin ti wahala kọkọ bẹ silẹ lowurọ Ọjọbọ ti wọn si kede pe ko si ohun to n jẹ idibo naa mọ atipe awọn ko nipin ninu rẹ mọ.

Wọn fi ẹsun kan gomina ipinlẹ Ekiti pe oludije kan to n ṣe agbodegba fun lo n da madaru silẹ ninu eto naa.

Wọn fẹsun kan oludije kan lara wọn pe o ti ragabo awọn ohun elo idibo naa ti o si ti n kọ ọ nibiamu oẹlu ohun to fẹ.

Atẹjade ti igbimọ naa fi sita ṣalaye pe aparo kan ko ga jukan lọ lori eto naa

Atẹjade naa ti akọwe igbimọ naa, Ọgbẹni Victor Ọlabimtan ṣalaye pe gbogbo awọn oludije lo pawọpọ yan awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti wọn lo fun idibo naa.

Amin iyasọtọ kan

Olùdíje gómìnà APC méje nínú mẹ́jọ fọnmú l'Ekiti lórí ìbò abẹ́nú

Awọn alatilẹyin awọn oludije gomina ni Ekiti to n se iwọde

Wahala ati bilisi lo bẹ silẹ nibi igbaradi eto idibo lati yan oludije ti yoo gbe aṣia AapC ni ibo gomina ipinlẹ Ekiti to n bõ losu kẹfa.

Ni ojumọ ọjọbọ lawọn oluwode kan ti kọkọ ya bo olu ileeṣẹ ẹgbẹ iselu APC to wa lagbegbe Ajilosun nilu Ado Ekiti nibi ti wọn ti n fi ẹhonu han pe ọkan lara awọn oludije naa ti se ayederu.

"Loru moju ni wọn ti tẹ ibo mọju arumọjẹ ni wọn kan fẹ wa ṣe lowurọ yii"

Bi iwode naa se n lọ pẹlu oniruuru iwe pelebe alakole lawọn janduku kan ya bo wọn pẹlu okuta ati ibọn.

Lakolako ni iro ibọn naa bẹrẹ si ni dun ti awon eeyan si fọnka. Gbogbo awon to ni ṣọbu sibẹ ni wọn bẹrẹ si nii ti ṣõọbu wọn.

Awọn alatilẹyin awọn oludije gomina ni Ekiti to n se iwọde

Ifarahan awọn oludije kan si olu ileesẹ naa lo mu ki alaafia diẹ ko pada sagbegbe naa.

Lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ awọn oludije ti n ṣe ipade lati mọ o a abayo si laasigbo yii

Awọn alatilẹyin awọn oludije gomina ni Ekiti to n se iwọde ni olu ile ẹgbẹ oselu APC
Amin iyasọtọ kan

Ijọba Ekiti ti ile ẹkọ pa nitori ibo abẹnu APC:

Wayi o, Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede oni Ọjọbọ gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun gbogbo awọn ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ni ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti oludari ileẹkọ nileeṣẹ eto ẹkọ nijọba ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni O.R. Ajayi fi sita rọ awọn adari ati olukọ ileẹkọ to jẹ tijọba ati aladani lati tẹle aṣẹ naa.

Bi o tilẹ jẹ pe wọn ko sọ idi ni pato ti wọn fi gbe awọn ileẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ti pa, iwadii BBC News Yoruba fihan pe ko lee ṣai nii ṣe pẹlu eto idibo lati yan oludije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

Eto idibo abẹnu naa ni yoo waye ni gbogbo wọọdu mẹtadinlọgọsan (177) kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun n'ipinlẹ Ekiti.

Àkọlé fídíò, Omi Daji: Odò tó dédé sàn jáde tí kìí gbẹ tòjò tẹ̀ẹ̀rùn, wọn kìí pa tàbí jẹ ẹja inú rẹ̀

Ìlànà gbogbo wa lá dìbò ni ẹgbẹ́ onígbálẹ̀ yóò lò láti yan olùdíje gómìnà

Ilana oju awo lawo fii gbọbẹ ti oloyinbo n pe ni "direct primaries" ni ẹgbẹ oṣelu APC fẹ lo fi yan oludije rẹ lọtẹ yii.

Ni Ọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP seto idibo lati yan oludije tirẹ ninu eyi ti Ọtunba Bisi Olayinka ti kogoja pẹlu ibo asoju ọrinlelẹgbẹta o din mẹsan an (671).

Ero idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti yoo waye ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa ọdun 2022 gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC ṣe gbe e jade.

Bi idibo abẹnu ẹgbẹ APC ba si se n lọ ni Ekiti, la maa mu wa fun yin.