Deposed Deji of Akure: Ọba Adesina sọ àsọtẹ́lẹ̀ kó tó kú pé ọmọbíbí Akure yóò jẹ ààrẹ Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Dapo Adepoju
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ti kede pe Deji tilu Akure tẹlẹ amọ ti wọn rọ̀ loye, Alayeluwa Ọba Oluwadamilare Adesina Adepoju Osupa Kẹta ti waja.
Atẹjade kan Ọmọọba Dapo Adepoju, tii se agbẹnusọ fun mọlẹbi ọba Adesina ti idile oye Osupa fisita fawọn akọroyin, lo fidi isẹlẹ naa mulẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, Owurọ Ọjọbọ tii se oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kinni ọdun 2022 ni Kabiesi ana naa dagbere faye pe o digbose lasiko aisan ranpẹ.
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
- Erin tẹ arìnrìn-àjò pá níbi tó ti ń ṣẹ̀yọ́
- Pásítọ̀ mi bá àbúrò mi ṣe àṣemáṣe, gba mílíọ́nù àkọ́kọ́ tí mo pa bíi òṣèré tíátà, ó tún já ojú òpó ayélujára mi gbà - Toyo baby
- Ọwọ́ Sọ́jà tẹ 100 afurasí jàńdùkú tó fẹ́ da ìbò abẹ́nú PDP rú l‘Ekiti
- Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó ní Buhari ti kú, Jubril Sudan ló ń darí Nàíjíríà
- Timothy Adegoke yóò wọ ilẹ̀ sùn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, bí ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ rèé
- Ìyè èèyàn mélòó ní wọ́n dáná sun pẹlú Kábíyèsí Agodo?ọlọ́pàá tú àṣírí
- Afenifere ń gbèrò láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, àgbà Yoòbá kan ní àbùkù ni yóò gbẹ̀yìn rẹ̀
Bawo ni Oba Adesina se dagbere faye?
Ọmọọba Adepoju salaye ninu atẹjade naa pe Ile iwosan adani kan to wa nilu Abuja ni oloogbe naa ti mi kanlẹ.
Amọ ko mẹnuba iru aisan to n se oloogbe naa, ko to dagbere faye.
Sugbọn o fikun pe Kabiyesi naa gbadura fun idagbasoke ilu Akure ati alaafia rẹ, ko to ki aye pe o digbose.
Awọn ọrọ ikẹyin ti Ọba Adesina sọ ko to dagbere faye:
Atẹjade iku Ọba Adesina Adepoju sisọ loju rẹ pe oloogbe naa ni oun gbiyanju agbara oun lati daabo bo awọn eeyan oun lasiko ti oun wa lori itẹ bii Deji tilu Akure.
O ni "Ọlọrun lo jẹ ko seese fun mi lati jẹ ọmọ bibi agboole oye Osupa ti yoo gori itẹ Deji ilu Akure lẹyin ọgọrun ọdun ti idile oye Ojijigogun ti jọba kẹyin."
Oloogbe naa rọ awọn eeyan ilu Akure lati maa gbe ni alaafia ati isọkan.
Ko to mi kanlẹ, Ọba Adepoju sọ asọtẹlẹ pe ilu Akure yoo pada ga siwaju si, ti ọmọ bibi ilu Akure yoo si di aarẹ Naijiria.
Awọn aseyọri Ọba Adesina lasiko to wa lori itẹ:
Ọba Adesina Adepoju lo se amusẹ ofin owo ori ọja ti ko gunpa lasiko to wa lori itẹ.
Bakan naa lo gba akoso ibudo igbafẹ Ilula pada fun ilu Akure lọwọ awọn alagbara
Oun naa lo tun pese eto aabo to peye, to si tun mu ki idajọ ododo fẹsẹ rinlẹ.

Oríṣun àwòrán, The Nigeria Voice
Ta ni Ọba Oluwadamilare Adesina tí wọn yọ loye, to ki aye pe o digbose?
Ọba Oluwadamilare Adesina Adepoju lati idile oye Osupa lo gori itẹ lẹyin ti Deji tilu Akure, Ọba Adebobajo Adesida papoda.
Asiko ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Dokita Olusegun Mimiko si jẹ́ gomina ni Ọba Adesina gba ọpa asẹ gẹgẹ bii Deji tilu Akure.
Amọ ko pẹ ti oriade naa gori itẹ, ti ariwo fi ta nipa ija nla to waye laarin rẹ ati kan ninu awọn Olori rẹ, Bolanle.
Iroyin sọ pe Ọba Adesina na Olori Bolanle nita gbangba loju popo ti ọpọ ero pejọ si, ti olori naa si tun ni o da eroja ibilẹ kan papọ mọ eeru eyi to ku si oun lara.
O ni eeru naa lo n bo oun lara, ti gbogbo ara oun si ti bajẹ.
Ko pẹ si akoko naa ti wọn yọ ba Oluwadamilaye Adesina Adepoju loye gẹgẹ Deji tilu Akure eyi to waye ni ọjọ Kẹwa, osu Kẹfa ọdun 2010.
Kabiyesi ana naa si lo waja lẹyin ọdun mọkanla to ti kuro lori itẹ.
Ọba Adebiyi Adesida si lo gori itẹ bii Deji tilu Akure lẹyin ti wọn rọ Adesina loye.
Nigba ti Ọba Adesida waja, Adesina tun gbiyanju lati gori itẹ awọn babanla rẹ pada amọ ẹpa ko boro mọ, ti wọn si fi ẹlomiran jọba.

















