Kakwenza Rukirabashaija: Òǹkọ̀wé tó dèrò àtìmọ́lé nítorí ó bú Ààrẹ lórí Twitter gba ìtúsílẹ̀

Kakwenza Rukirabashaija

Oríṣun àwòrán, HEBobiwine

Onkọwe kan ti wọn fi si atimọle lori ẹsun pe o bu Aarẹ orilẹ-ede Uganda ti gba ominira bayii.

Ominira yii lo n waye lẹyin ti wọn tun fi ṣikun ofin muu botilẹ jẹ pe ile ẹjọ kan ti kọkọ dajọ pe ki wọn jọwọ rẹ.

Agbẹjọro rẹ sọ fun awọn akọroyin pe awọn ọmọ ogun lo lọ ja onkọwe ọhun, Kakwenza Rukirabashaija, si ẹnu ọna ile rẹ to wa ni iha ila oorun Uganda.

Iyawo rẹ si ti fidi iroyin naa mulẹ.

Agbẹjọro rẹ ni ara okunrin naa ko ya, ati pe o ti lọ sile iwosan fun itọju to peye.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Ki ni ẹṣẹ Kakwenza to fi di ero atimọle?

Wọn fẹsun kan onkọwe naa, to ti gba oniruru ami ẹyẹ, pe o sọrọ kobakungbe si Aarẹ Yoweri Museveni, ati ọmọ rẹ, ọgagun Lt Gen Muhoozi Kainerugaba, loju opo Twitter.

Ṣaaju ni ile ẹjọ kan ti kọkọ gba beeli rẹ niluu Kampala, amọ wọn tun fi panpẹ ofin mu lai nidi kan pato.

Agbẹjọro rẹ sọ pe awọn kan ti ko wọ aṣọ agbofinro ni wọn ji gbe ninu ẹwọn to wa lọ si ibi kan ti ẹnikẹni ko mọ nipa rẹ.

Onkọwe naa gba ami ẹyẹ fun iwe kan to kọ nipa iwa ajẹbanu lorilẹ-ede rẹ lọdun 2020, eyii to pe ni "The Greedy Barbarian."

Bakan naa lo tun gba ami ẹyẹ "PEN Pinter Prize" lọdun 2021, gẹgẹ bii ọkan lara awọn onkọwe to gboju-gboya julọ lagbaye.