Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ
Ọjọ nla, ọjọ manigbagbe ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹrinlelogun osu Kinni ọdun 2022 yoo jẹ ninu itan ilu Agodo to wa ni ijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun.
Idi ni pe isẹlẹ aramọnda ti ko waye ni ilẹ Yoruba waye ninu ilu naa ni ọjọ ta n wi yii, ti awọn janduku kan sun oriade ilu naa mọ inu mọto rẹ pẹlu epo Pẹtiroolu.
Se ni ara gbogbo ọmọ Yoruba bu mọ asọ lati gbọ nipa isẹlẹ yii, ti oniruuru ibeere si n gba ẹnu wọn pe bawo niisẹlẹ naa se waye nilu ilu ti awọn agbofinro wa.
- Aráàlú fẹsẹ̀ fẹ bí jàndùkú ṣe dáná sun ọba wọ́n àti èèyàn mẹ́ta míì l‘Ogun
- Ìyè èèyàn mélòó ní wọ́n dáná sun pẹlú Kábíyèsí Agodo?ọlọ́pàá tú àṣírí
- Kí ló dé tí ọba méjì fi ń dé àdé nílùú Ikere Ekiti?
- Wo Omi-Dájì, odò ìsẹ̀ǹbáyé tó ń fún àgàn lọ́mọ, ṣe ọ̀pọ̀ ìwòsàn tó lágbára
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Michael Jackson, ọkùnrin tó sọ ara rẹ̀ di obìnrin kó sí pańpẹ́ EFCC
- Kí ló pa akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ Nàíjíríà tó kú lọ́jọ́ kejì tó dé ilé ẹ̀kọ́ ní Ukraine?
- Pásítọ̀ mi bá àbúrò mi ṣe àṣemáṣe, gba mílíọ́nù àkọ́kọ́ tí mo pa bíi òṣèré tíátà, ó tún já ojú òpó ayélujára mi gbà - Toyo baby
Ọna lati tu isu de isalẹ ikoko lo gbe BBC Yoruba lọ silu Agodo lati mọ ohun to sokunfa idi ti awọn janduku se wa sun Alagodo tilu Agodo, Ọba Ayinde Odetola mọ inu ọkọ rẹ.
Ki lo sẹlẹ ni ilu Agodo?
Nigba ti BBC Yoruba gunlẹ sinu ilu naa to wa lẹba ilu Papalanto ni eti ilu Ifo, a ri pe paroparo ni ilu naa da lai ri ẹyọ eeyan kan soso.
Koda, awọn ẹgẹ ti wọn rẹ sinu amu onirọba wa nilẹ, ti ko si si ẹni ti yoo yan wọn ni gaari.
O si daju saka pe lootọ ni isẹlẹ abami waye ninu ilu naa, ti ọ̀fọ̀ nla si sẹ.
Nigba to ya, a se alabapade Baalẹ ilu naa, Oloye Ajani Sotade, ẹni to se alaye bi isu se ku ati bi ọbẹ se bẹ nipa isẹlu ipaniyan ọhun.
Inu Posi ni awọn janduku ko ibọn si wọle pa ọba wa - Sotade
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Sotade ni se ni awọn janduku to sisẹ ibi yii gbe posi sinu mọto wọn, wọ inu ilu naa wa.
O ni wọn ja ewe si ara iwaju ati ẹyin mọto naa, tawọn araalu si ro pe oku ni wọn n gbe wọle bọ wa sin lai mọ pe ogun ni wọn wa ja.
O fikun pe se ni ọpọ ibọn kun inu Posi naa, bi wọn si se wọ inu ilu, ti wọn ri mọto Kabiyesi to yọ llọọ̀kan, ni wọn bẹrẹ isẹ ibi wọn.
Baalẹ ni se ni wọn n yinbọn tako tako soke laibikita, ti ọrọ si di boo lọ, ko yago fun mi.
O ni ki awọn si to mọ ohun to n sẹlẹ, wọn ti dana sun ọba awọn lai si ẹni to le gba silẹ.
Aarin awọn ẹgẹ ni mo sun mọju ninu oko, n ko ri aya atawọn ọmọ mi:
Ninu ọrọ rẹ, Oloye Sotade ni iru ko tii roju, tabi raye lati ọjọ ti isẹlẹ naa ti waye.
O ni gbogbo awọn araalu ti sa lọ sawọn abule to mule ti wọn, ti oun ko si ri aya atawọn ọmọ oun, koda, oun ko mọ ibi ti gbogbo wọn wa bayii.
Sotade fikun pe aarin ẹgẹ to wa ninu oko oun ni oun sun mọju ọjọ keji nibi ti oun gan sa lọ.
O tun sọ fun BBC pe oun ko ti fi ounjẹ kan ẹnu lati ọjọ ti isẹlẹ naa ti waye nitori ẹru gan n ba oun lati ran eeyan ni ounjẹ nitori idagiri miran.
Baalẹ naa wa fi orukun rẹ to bo pẹlu ẹjẹ han BBC lasiko to n sa lọ.
A n fẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati pese aabo, ki iranro ma baa pada wa:
Baalẹ Sotade ni ẹru to n ba awọn bayii ni pe awọn ẹbi Ọba ti wọn pa le fẹ pada gbẹsan bi wọn se pa eeyan wọn, ki wọn tun ko ogun miran wa sinu ilu naa.
O wa n ke si ijọba lati tete pese eto aabo to peye sinu ilu naa, eyi ti ko ni jẹ ki iru ikọlu ibi yii tun pada waye lati ọdọ ẹnikẹni.
O fiikun pe ti idaniloju eto aabo to peye ba wa, gbogbo araalu to salọ ni yoo pada wale.
Alagodo nikan ni wọn pa, wọn ko pa awọn miran pẹlu rẹ - agbẹnusọ Ọlọpaa Ogun:
Lẹyin ta kuro ninu ilu naa la morile olu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa nilu Abeokuta lati mọ ibi ti iwadii awọn ọlọpaa de duro nipa isẹlẹ naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni eeyan kan soso ni wọn pa ninu isẹlẹ naa, wọn kii se eeyan mẹta bi ọpọ iroyin se n sọ.
Oyeyemi ni ọwọ ọlọpaa ko ni pẹ tẹ awọn janduku to pa Alagodo nitori iwadi ti dide, to si ti n lọ lọwọ nipa isẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun wa ke sawọn araalu pe ki wọn pada wa sile wọn nitori awọn ọlọpaa ti wa ninu ilu naa lati pese aabo to peye fun wọn.
O tun fi ọwọ idaniloju sọya pe ko si ẹnikẹni ti yoo dide lati gbẹsan kankan, ti mọlẹbi ọba to ku naa si ti fi ọwọ sọya pe awọn ko ni lọ gbẹsan lara ẹnikẹni.



