Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Laipẹ yii ni iroyin gba ilẹ kan nipa ọdọkunrin olorin kan to gbe orin Zazzu jade eyi to n mi igboro titi.

Ati ọmọde, ati agbaagba lo n jo si orin naa, ti ọpọ eeyan si n beere pe nibo ni iru olorin bayi wa lati ọjọ yii, nibo si lo ti jade wa.

Eyi ko si sẹyin iru ohun orin rẹ to yatọ ati ilana ijo pẹlu imura rẹ to se ara ọtọ.

Idi ree ti BBC Yoruba fi wa olorin Zazza Zeh kan lati fi ọrọ wa lẹnu wo, ka si mọ bo se bẹrẹ igbe aye rẹ, de ibi to de bayii.

Yoruba ni ẹni ti yoo ba ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ ni ọrọ ri fun Habeeb Badmus Okikiola ti ọpọ eeyan mọ si Portable Zazzu ẹni ti oju rẹ ti ri to nidi orin kikọ, ko to wa ja oju ọna.

Ta ni Portable to kọ orin Zazzu Zeh, to n mi igboro titi?

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Portable ni ọmọ bibi ilu Abeokuta ni oun amọ Sango Ota ni wọn bi oun si, ti oun si gbe Mushin Olooṣa dagba.

O fikun pe ọdun kẹẹdogun ree ti oun ti bẹrẹ isẹ ofin kikọ amọ ọdun kẹwa ree ti oun ti di gbajumọ, ki Ọlọrun to wa ni ko zeh fun oun ni aipẹ yii.

Nigba to n salaye awọn ohun ti oju rẹ ti ri sẹyin. Portable tun salaye bi awọn eeyan bii ọdunrun se dawọ bo lati ja si ihooho ọmọluabi lori ẹsun pe o ji kẹkẹ Maruwa.

Ọrọ pọ, ti Portable ba wa sọ, ẹ maa kalọ lati gbọ.