Yoruba movies: Portable ní Dec 2018 ni ọ̀rẹ́ gba owó ọkọ̀ lọ́wọ́ òun láì ri mọ́

Gbajugbaja Oṣere Portable

Oríṣun àwòrán, mrportableharejan/ instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Yoruba ni ṣun mọ ni laa mọ ìṣe ẹni, eeyan gbe okeere niyi, inu si jin, o ju ọrun lọ.

Awọn owe yii lo n salaye iru ipo ti gbajumọ oṣere tiata kan, Olu Olowogemo, ti ọpọ eeyan mọ si Portable wa lonii tii ṣe ayajọ ọjọ ibi rẹ.

Nigba to n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da ẹmi rẹ si lati ri ọdun tuntun loke eepẹ, Portable tun wa n salaye tẹdun tẹdun ọkan nipa awọn ipenija ko n koju rẹ.

Nigba to n salaye yii ni oju opo Instagram rẹ, mrportableharenjan, portable ni o dun oun pe oun ko ni ọkọ nidi, lonii ọjọ ibi oun, ti oun si n fi ẹsẹ rin kiri.

"Iji orisirisi lo ja mi, amọ mo sọpẹ. Lara iji naa si ni pe nipari ọdun 2018, ọrẹ mi kan to wa nilu oyinbo pe mi, o ni ki n ta ọkọ kan ṣoṣo to wa nidii mi, ki n si ko owo ransẹ, ki oun ba mi fi owo kun, lati ra mọ́tò tuntun."

"O ni maa gba ọkọ naa ni oṣu kinni ọdun 2019, sugbọn lati igba naa, n ko gburo owo pẹlu mọto tuntun, mo ni orukọ, mo gbajumọ sugbọn ẹsẹ ni mo n rin kaakiri, mo tun n gun ọkada kiri."

Gbajugbaja Oṣere Portable

Oríṣun àwòrán, Portable

Portable ni ti oun ba fẹ lọ ṣíṣe ni ibi kan, oun maa n lọ wọ ọkọ ni gareeji ni, iriri ti oun si n ri nibẹ, ko dara rara,oun si mọ pe inu Ọlọrun ko le dun si ọrẹ oun.

Nigba to n salaye lori igbesẹ to fẹ gbe lori iṣẹlẹ yii, Portable ni "Ọjọ ibi mi ọdun yii tun ko lai jẹ ki n ri ọkọ lo, mo wa fun ni ọjọ perete, ti ko to ọjọ mẹwa lati da owo naa pada gẹgẹ bo ti ṣe ileri."

"Bi ko ba wa da owo naa pada, maa fi fọto rẹ sita, pẹlu orukọ rẹ, ibi ti wọn ti bii, orúkọ Baba rẹ ati ibi to n gbe nilu oyinbo, nọmba foonu rẹ, oju opo Facebook rẹ, gbogbo rẹ ni mo fẹ pariwo fun araye."

Portable ni oun yoo jẹ ki gbogbo ololufẹ oun kaakiri agbaye mọ, ki wọn gbeja oun, ti ọrẹ oun naa ko si ni ri ibi rin si, eyi ti yoo jẹ ko mọ pe nnkan ju nnkan lọ.

Portable wa n rọ awọn ololufẹ rẹ jakejado agbaye lati ran oun lọwọ, gba ẹtọ oun fun oun, ni kete ti oun ba pariwo ọrẹ oun naa sita.