Kogi alleged rape: Agbẹjọ́rò fún arábìnrin tó fẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan kọmíṣọ́nà Kogi ní ó ṣeéṣe kí ìyípadà rẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà ó lọ́wọ́ àwọn alágbára nínú

Oríṣun àwòrán, Elizabeth adeniyi
Ṣe ẹranti arabinrin kan to fi ẹsun ifipabanilopọ kan kọmiṣọna kan ni ipinlẹ Kogi ni oṣu diẹ sẹyin?
Agbẹjọrọ fun arabinrin naa ti ni o ṣeeṣe o ko jẹ pe awọn alagbara ti fẹ maa fi agbara wọn lo ipo lori ọrọ naa eyi to ni o ṣeeṣe ko fa bi arabinrin naa ṣe wa n ṣe bi ẹni ni iyipada ọkan lori ọrọ naa lẹnu lọwọlọwọ yii.
Amofin Dorothy Njemanze to ba BBC News Yoruba sọrọ lori ọrọ kan ti wọn ni arabinrin naa kọ loju opo Facebook rẹ ninu eyi to ti ki kọmiṣọna ọhun ku oriire ọjọ ibi rẹ ṣalaye pe ko si idi fun arabinrin yii lati yi pada lori ẹjọ naa ti kii ba ṣe pe awọn alagbara ti n lo agbara wọn lori iṣẹlẹ naa.
Ninu oṣu Kẹta, ọdun 2020, ni iroyin jade pe kọmisana fun awọn alumọni inu omi nipinlẹ Kogi, Abdumumini Danga, fi ipa ba ọmọbinrin kan lopọ, to si tun lu u.
- Ayálégbé wa tó fi tipá já àbálé mi ṣe àkóbá fún ìgbé ayé mi - Foluke Daramola
- Ọmọ pupa làwọn olólùfẹ́ wa fẹ́ wò nínú fíìmù làwọn òṣèré tíátà fi ń bóra - Muka Ray
- Ìjà Awolọwọ, Akintọla àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Gómìnà Ondo Akeredolu ṣí ilẹ̀kùn ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí sílẹ̀ fún ìjọ́sìn
- Ṣé olorì ṣì ni Badirat Ọla láàfin ikú bàbá yèyé?
Ọmọbinrin naa, Elizabeth Oyeniyi, ninu fidio ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ajọ ajafẹtọ Dorothy Njemanze Foundation, sọ pe kọmisana naa ji oun gbe, to si tun lu oun nitori pe oun gba a nimọran pe ko tọju ẹbi rẹ.
O fẹsun kan pe kọmisana naa ran awọn kan wa a gbe oun lati ilu Okenne lọ si Lokoja, nibẹ lo si ti lu oun ati aburo rẹ to jẹ ọrẹ oun ni ilukulu.
Koda, iroyin sọ pe gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello paṣẹ pe ki iwadii o waye lori ẹsun naa, to si ni ki kọmisana lọ ko lọ rọọkun nile naa.
Sugbọn nkan to ya ọpọ eeyan to gbọ si ọrọ naa nigba naa lẹnu, ni bi wọn ṣe ri ti ọmọbinrin naa fi aworan kọmisana naa sori ayelujara Facebook rẹ, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun, ọdun 2020.
To si ki i ku ayẹyẹ ọjọ ibi. O kọ ọ pe:
"Mo kan fẹ ki o mọ pe mo n ki ọ ku ọjọ ibi. O damiloju pe o n jẹgbadun. Si awọn to ro pe ọta ni emi atiẹ yoo jẹ titi lai, ki lero yin bayi?"
Amofin Dorothy Njemanze to jẹ Oludari ajọ aṣeranwọ , Dorothy Njemanze foundation tun ṣalaye fun BBC pe awọn fura pe ọrọ naa ti n ni iwa mago-mago ninu ni.

Oríṣun àwòrán, Elizabeth Oyeniyi
O sọ pe wọn ko ti i yanju ọrọ naa, nitori pe ọpọ eeyan to jẹ gbajumọ nilu ni orukọ wọn ti jẹyọ ninu ẹsun naa.
"Fun ọpọlọpọ ọsẹ, a mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ranṣẹ pe kọmisana naa, nkan ti mo ro ni pe iwa ibajẹ ti fẹ ẹ gbakoso ẹjọ naa.
Alaafia onibaraa mi lo jẹmilogun ju bayii. Ao si fi atẹjade sita laipẹ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O sọ pe "ko si nkan to pamọ fun mi nipa nkan to n lọ lori ayelujara onibaraa mi, ṣugbọn, ṣe oun lo n kọ wọn?''
"Ohun to damiloju ni pe iwa ibajẹ lo n ja takuntakun bayii."
O jẹ nkan to mu ifura dani pe ọmọbinrin naa kọ iru nkan bẹ ẹ sori ayelujara lasiko ti iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ẹsun to fi kan kọmisana."
Bakan naa ni Arabinrin Njamanze sọ pe ajọ oun yoo fi atẹjade sita lori ọrọ naa.
Igbiyanju lati ba ijọba ipinlẹ Kogi sọrọ, ṣugbọn ko tii so eso rere.
Kini akọṣẹmọṣẹ sọ nipa iyipada ọkan ẹni ti wọn fi ipa balopọ tabi hu iwa ipa si?
Onimọ nipa ihuwasi ẹda, Ọjọgbọn Oni Fagboungbe, ṣalaye idi to le mu ki obinrin ti wọn fi ipa balopọ, tabi hu iwa ipasi pada sọ pe oun ko ṣe ẹjọ mọ.
O ni bi kaluku ṣe n gba ọrọ mọra yatọ sira wọn. O ni lọpọ igba, itiju nkan ti awọn eeyan awujọ yoo sọ nipa ire eeyan bẹ ẹ le mu ki o sọ pe oun ko ṣe ẹjọ mọ.
"O tun le jẹ pe nitori pe iru obinrin bẹ n ro bi ọjọ iwaju rẹ yoo ṣe ri, paapa ni ibamu pẹlu ọrọ Yoruba pe a kii ti kootu de, ka ṣe ọrẹ"
Bakan naa lo sọ pe aṣa ati iṣe ẹya ti iru obinrin bẹ ẹ ti wa tun le ni ipa lori igbesẹ rẹ. Nigba miran, awọn agbalagba ilu tabi ẹbi le da si iru ọrọ bẹ l, ki wọn o si parọwa fun obinrin naa.
Ọjọgbọn Fagboungbe sọ pe o maa n ṣẹlẹ daada ti obinrin ti wọn hu iwa ipa si, tabi fi ipa balopọ yoo sọ pe oun ko ṣe ẹjọ mọ, lẹyin ti ọrọ ba ti de ileeṣẹ ọlọpaa lọ.
O tun sọ pe awọn ti kii ti ẹ sọ sita, tabi lọ si ileeṣẹ ọlọpaa ti iru nkan bẹ ẹ ba ṣẹlẹ si wọn, pọju awọn to n sọ sita lọ.












