Kí ló dé táwọn olólùfẹ́ Omijé Ojúmi ṣètò ayẹyẹ ìdágbére fún un ní Kwara láì náàní àṣẹ tí ẹbí rẹ̀ pa lórí ìsìnkú rẹ̀

Awọn olubanikẹdun jokoo lori aga, wọn wọ aṣọ dudu, aworan Omije Ojumi wa ni apa ọtun

Oríṣun àwòrán, BBC/Bunmi Akinnaanu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹsẹ o gbero nibi ayẹyẹ aṣalẹ orin ati idagbere ti wọn seto fun gbajugbaja Olorin ẹmi un ni Ajihinrere Bunmi Akinnanu ti gbogbo eeyan mọ̀ si Omije ojumi.

Eto naa to waye ni gbọngan ìjọ ECWA to wa ni agbegbe Challenge ni ilu Ilọrin olu ilu ipinlẹ Kwara.

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awon olorin ẹmi ni ipinlẹ Kwara ati lawọn ipinlẹ mii lo peju sibẹ

Ninu ọrọ rẹ ọkan lara awọn ololufẹ rẹ to gbe eto naa kalẹ Pastor Israel Israel sọ pe, titi lae lawọn yóò ma se ranti Omijé ojumi.

Pastor Israel sọ pe, iku rẹ bawọn lojiji pẹlu alaye pe, kìí jina si ilu Ilọrin to si ko gbogbo awọn olorin to ṣẹṣẹ n dide mọra.

Lasiko to n ba asoju kọroyin ile iṣẹ wa BBC Yoruba sọrọ gbaju gbaja olorin ẹmi Ajihinrere Elijah Akintunde ti gbogbo eeyan mọ si Ọlọrun o sọ bẹẹ sọ pe, olóògbé naa jẹ eekan ninu olorin ẹmi.

O fikun pe, iku rẹ ba oun lọkàn jẹ pupọ pẹlu alaye pe, olóògbé naa jẹ ẹlẹmii irẹlẹ nigba to wa laye to si maa n gbadura gidigidi.

O fikun pe, oloogbe naa kii foju di eniyan rara o si jẹ onigbagbọ ododo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọro wọn, awọn olorin ẹmi mii, Taye ati Kehinde Adegbodu sọ pe, adanu nla ni iku Omijé Ojumi jẹ lagbo awọn olorin.

Lasiko to n waasu nibi eto naa Wòlíì Saminiye lati ilu Ibadan, ni ipinlẹ Ọyọ sọ pe, akoko olorin emi naa lo to.

O gba awọn olorin ẹmi to ku ni imọran lati gbe ile aye se rere, o ni ki wọn sì máa ṣe rere ni gbogbo igba.

O woye pe Omijé Ojumi ti lapa rere ni ile aye pẹlu orin rẹ to mi gbogbo agbaye ti wọn pe ni Omijé ojumi.

Ọgọọrọ awọn olubanikẹdun to wa nibi eto naa ni wọn sọ nipa igbesi aye olóògbé.

Ọpọ eeyan o ti ẹ le pa ẹkun mọra ti wọn si n bu sẹkun lasiko kikọ orin idagbere ati titan abẹla fun olóògbé naa.

Lasiko to n sọrọ, olorin ẹmi Bunmi Taiwo lati ilu Ibadan ni awọn o le gbagbe Bunmi Akinnanu Omije ojumi fun ipa nla to ko nidii iṣẹ ori ẹmi.

Eto titan abẹla ati ọrọ iwuri ati imunnilọkanle ni wọn fi pari eto naa.

Nipari ohun gbogbo, akanse adura waye fun ọmọ oloogbe ati idile rẹ.

Ọpọ awon olorin emi to wa nibi eto naa ni wọn kọrin lọkan-o-jọkan lati fi ṣe idaro akẹgbẹ wọn.

Eto naa lawọn olorin ẹmi ni ipinlẹ Kwara ati awọn ololufẹ gbajumọ Olorin ẹmi naa ni ipinlẹ Kwara ṣeto fun oloogbe lati fi ṣe imọriri igbe aye rẹ.

Tẹ o ba gbagbe gbajumọ olorin ẹmi Bunmi Akinnanu ti gbogbo eniyan mọ si Omije Ojumi jade laye lọjọru, ọjọ Kẹrinla oṣu Kiini, ọdun 2026.

Àwọn olùbánikẹ́dùn níbi ìsìn ìdágbéré fún Omije Ojumi