Nollywood: Saheed Balogun àti Shina Peters lọ sí ilé Ààrẹ Buhari lÀbuja, wọ́n gba àmì ẹ̀yẹ

Oríṣun àwòrán, femi adesina/facebook
Ki ni agba oṣere, Saheed Balogun ati agba akọrin Sir Shina Peters lọ ṣe ni ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria nilu Abuja, nibi ti aworan wọn ati awọn atawọn eekan elere tiata miran ti jẹyọ pẹlu amugbalẹgbẹ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adesina.
Agba oṣere ati akọrin meji naa wa lara ikọ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ' Ambassadors of Voice for Change' to ṣe abẹwo si Ọgbẹni Fẹmi Adesina nibi ti wọn ti fi ami ẹyẹ da a lọla nilu Abuja.
Awọn agba osere bii Mr. Ibu, Onyekweli Harry B, Gentle Jack, Ben Kure atawọn eekan miran latiẹya gbogbo lorilẹede Naijiria wa lara awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa wa nibi abẹwo naa ti Ahmed Bala ko sodi lọ.
Amugbalẹgbẹ fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo naa wa kan sara sawọn agba amuludun ọhun fun ipa ti wọn n ko lati rii pe iṣọkan ati alaafia di igi alọye lorilẹede Naijiria.
Ọgbẹni Adeṣina fi kun un pe awọn olulaja atawọn to n lepa alaafia lorilẹede Naijiria nilo bayii, kii ṣe awọn ọbayejẹ ti yoo pagidina idagbasoko ati iṣọkan Naijiria.
Bakan naa lo tun ṣalaye pe ijọba Buhari yoo tubọ maa ṣe atilẹyin to ba yẹ fun awọn ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ takuntakun lati mu alaafia gbooro sii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post










