Ọwọ́ ti tẹ ọkunrin abani fi ẹru ránṣẹ kan, Emmanuel Samuel, lasiko to n sa lọ pẹlu ọkada ileesẹ to fi n sisẹ

omokunrin

Oríṣun àwòrán, others

Iroyin sọ pe lasiko ti awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun da a duro ni ilu Ogere ni ọwọ tẹ ẹ.

Gẹgẹ bi agbenusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ṣe sọ, ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2021, ni awọn ọlọpaa da a duro lori ọkada naa, ti wọn si beere àwọn iwe rẹ. Lẹsẹkẹsẹ si lo fi gbogbo rẹ han wọn.

Sugbọn nibi ti wọn ti n yẹ awọn iwe naa wo, ni wọn ṣe akiyesi pe ọjọ ti wọn fi orukọ ọkada naa silẹ lọdọ ijọba tako ọjọ ti wọn ra a lọ. Eyi to tumọ si pe wọn ti fi orukọ ọkada naa silẹ ki wọn o to o ra.

Nigba ti BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi fidiẹ mulẹ pe ootọ ni.

Ọgbẹni Oyeyemi sọ pe eyi gan-an lo mu ki ara fu awọn ọlọpaa naa, ti wọn fi gbe ọkunrin to gun ọkada naa lọ si agọ wọn.

"Asiko ti wọn n fi ọrọ wa a lẹnu wo lo jewọ pe ileesẹ kan ni Yaba, nipinlẹ Eko, lo gbe ọkada naa fun oun.

Àkọlé fídíò, Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

Ọjọ kẹta ti wọn gba a ṣíṣẹ́ lati ma a fi ẹrù ránṣẹ fun awọn onibaara, lo gbe ọkada salọ.

O ni oun pinnu lati gbe ọkada naa salọ, to si ṣe ayederu iwe ati nọ́mbà fun ọkada naa."

Bo ṣe jewọ yii lo mu ki oga ọlọpaa DPO ni ẹka Ogere, CSP Abiodun Ayinde, pe ileesẹ naa.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Ileesẹ naa sọ pe lootọ ni awọn ti n wa afurasi naa nipinlẹ Eko.

Wọn ni koda, o mọọmọ yọ ẹ̀rọ to n tọ pinpin kuro lara ọkada naa.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y