Traditionalist Oba Ogun: Oba Tejuosho ìlú tí wọn bá ti yọwọ awọn oniṣẹṣe kuro ninu oba jijẹ ko le roju raye

Oríṣun àwòrán, Oba Adetokunbo Tejuoso
Oba Dr Adetokunbo Okikiola Tejuosho, Olu Ile Kenta ti sọ fawọn oniṣẹṣe pe ijọba ko le yọwọ laelae ninu eto ifinijọba gẹgẹ.
Awọn ẹgbẹ oniṣẹṣe ẹka ti ipinlẹ Ogun ti kepe igbimọ aṣofin ipinlẹ naa yọwọ ninu abadofin ti yoo maa ṣakoso awọn lọbalọba nipinlẹ naa.
Amọ nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oba Tejuosho ni oniṣẹṣe kọ lo n yan ọba, ijọba lo n ti n yan ọba lati ọjọ to ti pẹ
''Mo bọwọ fawọn oniṣẹṣe, amọ nkan to yẹ ki ifẹhonuhan da le lori ni pe ki ijọba maa bawọn sọrọ lori ọrọ ọba jijẹ
- Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ tuntun sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò kí ọwọ́ ajínigbé má tẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́
- Àwọn Aṣòfin yọwọ́ nínú àbádòfin tí yóò máa fòfin de àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀hónúhàn
- 'Lóòtọ́ èmi ni mo ṣagbátẹrù òpó alátagbà Airtel lọ sí Ago Owu ṣùgbọ́n kìí ṣe àkànṣe iṣẹ́ agbègbè mi'
- Ohaneze Ndigbo lẹ́tọ̀ọ́ láti gba agbẹjọ́rò fún Nnamdi Kanu- Malami
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá
- Ààrẹ Buhari ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn sẹ́nétọ̀ 109 lálẹ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun
Kabiesi orile Kemta nipinlẹ Ogun ni: Kii ṣe oni lo ṣẹṣẹ bẹrẹ ti ijọba ti n yan ọba.
O yẹ ki wọn sọ pe ki ijọba maa bun wọn gbọ nipa ọrọ awọn lọbalọba ni, nitori ijọba ko le yọwọ ninu ifinijoye,'' Oba Tejuosho lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, others
Bakan naa ni Oba alade ọhun tun sọ pe ''ko si bi ijọba ṣe fẹ yọwọ awọn oniṣẹṣe naa ninu eto ifinijọba.
Ijọba gan an mọ pe awọn etutu wa ti eeyan gbọdọ ṣe ki o to jọba.
Ti wọn ba yọwọ oniṣẹṣe tabi awọn eletutu ninu ọba jijẹ, ilu ko le roju raye.''
Oba Tejuosho tun bu ẹnu atẹ lu awọn eeyan kan to maa pada si ẹsun kristẹni tabi musulumi lẹyin ti wọn ba jọba tan.
O ni ''ẹni to ba jọba ni ṣọọṣi tabi mọṣalaaṣi ko gba ile ijọsin lọ to ti jọba lọ.
Kabiesi ni: ke le jọba tan ki o wa sọ pe o di pasitọ tabi aafa.
Iṣẹṣe la n bọ ki awọn ẹsin ajeji to de,'' Oba Tejuosho lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Af24news
Àwọn oníṣẹ̀ṣe ń fẹ́ kí ìjọba yọ ọwọ́ nínú Ọba yíyàn ní ìpínlẹ̀ Ogun
Àwọn oníṣẹ̀ṣe ń fẹ́ kí ìjọba yọ ọwọ́ nínú Ọba yíyàn ní ìpínlẹ̀ Ogun
Awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun ti ke si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati yọwọ rẹ ninu abadofin kan to da lori bi wọn ṣe n yan ọba, awọn baalẹ, oloye atawọn igbimọ lọbalọba nipinlẹ ọhun.
Wọn ni ki awọn aṣofin ọhun dawọ iṣẹ duro lori abadofin naa ti yoo fun ijọba lagbara lati maa ṣakoso bi wọn ṣe yan ọba nitori kii ṣe iṣẹ wọn.
Agbẹnusọ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ ogun, Ifayemi Osunlabi sọ fun awọn akọroyin niluu Abeokuta pe ti abadofin naa ba le di ofin, yoo pa awọn etutu kan ti wọn maa n ṣe fun awọn to ba fẹ jẹ ọba ni ipinlẹ naa rẹ.
- Wo òtítọ́ nípa oúnjẹ Nódùùlù táwọn ọmọde máa ń jẹ
- Mi ò lè fọwọ́ sí àbáòfin kankan tí yóò fòfin de iṣẹ́ akọ̀ròyìn - Femi Gbajabiamila
- Irọ́ ni o! Awujale ilẹ̀ Ijebu kò wàjà, ẹ sinmi ariwo
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń gbé lẹ̀yìn tí wọ́n rí ẹ̀dà Covid-19 "Delta variant" tuntun níbẹ̀
- Ohaneze Ndigbo lẹ́tọ̀ọ́ láti gba agbẹjọ́rò fún Nnamdi Kanu- Malami
Osunlabi sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ jẹ ọba ni lati tẹle gbogbo awọn alakalẹ iṣẹṣe to wa nilẹ lati igba iwasẹ wa.
O ni ti wọn ba ṣe aṣeyọri ninu gbigbe ofin naa kalẹ tan, yoo tẹ ẹtọ awọn oniṣẹṣe mọlẹ, o si ṣeeṣe ko da wahala silẹ laarin ilu.
"Ẹnikẹni to ba ti jẹ Ọba ti di igbakeji oriṣa, irufẹ ẹni bẹẹ si ni lati tẹle awọn aṣa ati iṣẹṣe kan to ti wa nilẹ tipẹtipẹ."
Ifayemi Osunlabi wa ke si awọn aṣofin naa lati dawọ isẹ duro lori abadofin naa ki alaafia le jọba ni ipinlẹ Ogun.
O fi kun pe ofin ọhun yoo da wahala silẹ nipinlẹ Ogun, eyii ti yoo ṣoro lati yanju lọjọ iwaju.
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Wọ́n ti yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún Baba Ijesha ní Ireland kúrò lórí ayélujára
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń gbé lẹ̀yìn tí wọ́n rí ẹ̀dà Covid-19 "Delta variant" tuntun níbẹ̀
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
Gẹgẹ bii hun to sọ, ko si ohun to kan awọn aṣofin pẹlu ọrọ iṣẹṣe ati bi wọn ṣe n yan ọba ilu.
O pari ọrọ rẹ pe ọdun to kọja ni wọn kọkọ dabaa ofin naa ṣugbọn awọn oniṣẹṣe tako o, awọn ko si ni gba ki abadofin ọhun di ofin ni igbẹyingbẹyin.
- Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀
- Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí Sẹ́nétọ̀ Adelere Oriolowo, APC tó fi opó ẹ̀rọ ayélujára Airtel ṣe iṣẹ́ àkànṣe ìlú ní Osun
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
















