Noodles: Oúnjẹ aládùn ni àgbáyé mọ Nódùùlù sí

Udon ro núdùlù pọ̀ pẹ̀lú olú àti àwọn ẹ̀fọ́ lórísireísí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ebi ń pa yín bi?

Ó ṣeéṣe kí ènìyàn fàá gùn, raá ródóródó tàbi ṣeé ní bíbọ̀ kí a tún ṣe àdàlú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èròjà odò bíí edé, ẹja, akàn, ó tún lé jẹ́ wàá sá kí wọn si maa tàá nínú abọ.

Ohun kan ló dájú: Síṣe ní núdùlù, wọn a sèé, wọn sì ń jẹẹ́, ounjẹ yìí jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká àti ìtẹ́wọ́gbà lágbàyé gẹ́gẹ́ bi ounjẹ ti àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn páànù ìdáná, àti àwọn goro níwajú ìta sọọbu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, China, Ìpìlẹ̀ ilé núdùlù

1. Nódùùlù tí tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún

Lọ́dún 2002, abọ́ núdùlù kan tí tó égbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọn wúu lábẹ́ ilẹ̀ ní ẹkun Qinghai ní China.

Abọ́ tí wọn hú ọ̀hún tohun ti ǹkan to wà nínú ẹ ni wọn rí níbi ti wọn bòó mọ́lẹ̀ sí ní mítà mẹ́ta sí abẹ̀ ilẹ̀ ní Lajia, lágbègbè ti ilẹ̀ rírí tí ṣẹ̀lẹ̀ ní ní ọdun ppẹ́ sẹ́yìn

Núdùlù oní kíákíà ló maa ń fòlékè nínú omi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kan bu omi síi

2. Wọn dá núdúlù sílẹ̀ lati ṣẹ́gun ebi lágbàyé

Lẹ́yin ti Japan ṣegun nígbà ògun àgbáyé elékejì, à ti rí ounjẹ jẹ le koko, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń gbákàn lé ìrànwọ́ ilẹ̀ Amẹ́rikà.

Momofuku Ando, tó jẹ́ ọmọ Taiwan-Japan sùgbọ́n tó kùnà nínú ìṣòwò rẹ̀, ń wá ọ̀nà láti fún àwọn ọmọogun Japan tó wà nínú ìyàn lẹ̀yìn ogunàgbáye ẹlékejì, pẹ́lú èrò pé àláfíà yóò jọba tí àwọn ènìyan bá ti n jẹ àjẹyó àti àjẹ ṣẹ́kù.

Àkọlé fídíò, Royal Hugs Surprises: Ìyá ẹni ọdún 50 tó dọlọ́mọ láyé fi ìdùnnú hàn bí a ṣe kàn síi- Debor

Nítori náà, ó lo ọdún kan nílẹ̀ àhéré lẹ́yìkùlé Osaka, láì ṣe àárẹ̀ bótilẹ̀ jk pe bó ṣe ń ṣe àsìṣe bẹ́ẹ̀ ló ń gbàyànjú sìí, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìn bọ̀ ọ́ ṣe àṣeyọri láti ní ilé ounjẹ tí gbogbo ènìyàn mọ jùlọ lágbàyé.

Ọdún 1985 ní wọn kọ́kọ́ ta Núdúlù lágbàyé

Shelves stacked full of pots of instant ramen, at a convenience shop in Tokyo, Japan. O ri pẹpẹ ti wọn ti ń ta Nudulu ni Tokyo, Japan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, O rọrùn, ó rẹwà, pàtàkì jùlọ koi wọn rara bákan náa[ló ti di awo máleeló lágbàyé

3. Mílíọnù ènìyàn ló ń jẹ Núdùlù lágbàyé lójoojúmọ́

Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún ti Ando ṣe àwári Núdùlù, ó kéré tán ènìyàn tó dí díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún lánà sọ̀dúrún ló ń jẹ Núdùlù lójoojúmọ lágbàyé, gẹ́gẹ́ bi ẹgbẹ àwọn oni Nudulu ṣe sọ.

Ní ọdún tó kọjá nìkan àwọn ènìyàn ọgọ́rùn bílíọ̀nù ní wọn jẹ núdùlù lágbàyé, ti méjìdínlógójì nínú rẹ̀ sí wáyé ní gbùngbùn China.

Àkọlé fídíò, Kí ló dé tí ẹ kò fi kọ́ mi lédè Yoruba?

4.Orílẹ̀-èdè Japan ní Musiọmu mẹ́ta tí wọn fi sílẹ̀ fún Núdùlù

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ míléníọmú tí ìdìbò kan sì wáye, àwọn Japan gba wípé Nudulu ní ǹkan tó làmìlaka jùlọ ti àwọn ti gbéṣe

Akojópó Núdùlú Japanese

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Shirataki, Soba, Ramen, Sōmen, Udon, Hiyamugi, Tokoroten... A lè sọ pé núdùlù ń gbégbá orokè ní Japan

5. Ní Japan jíjẹ Núdùlù bí ẹni fa omi mú ní ọ̀nà to dara jù láti jẹ Núdùlù

Ní Japan fifa núdùlù pẹ̀lú ariwo nígba ti ènìyàn bá ń jẹ kìí ṣe ohun ti wọn ri bi ìwà ìbàjẹ́ bíkòṣe ohun amúyẹ pe ẹni to ń jẹ mọ rirì rẹ

Bí o bá jòkó síwájú abọ́ Núdúlù síwájú tó sì ń lo síbi onígi lati fini mọ̀nà ẹnu, lẹ̀yìn náà ni wọn o fèrè rẹ̀ sẹnu pèlú ariwo.

Eyi yóò fún ẹni to gbà ọ lálejo ní ìdánilóju pé o gbádùn ounjé to pèsè fún ọ

Cute Japanese girl, slurping noodles from a black bowl

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Licence to slurp

6.Núdúlù ní ounjẹ tó bá ofin mu ti wọn maa ń ta lagbà ẹwọn ní orilẹ̀-èdè Ameríkà

Nínú ìwádìí to wáyé láìpẹ́ yìí sàfihan pé núdúlù ti gbààyè sìgá bó ṣe jẹ ọ̀jà títà to wọ́pọ̀ nínú ọgba ẹwọn US

Bí wọn ṣe di owó ìtójú àwọn ẹlẹ́wọn kù, ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹwọn ni wọn rí ounjẹ to to fún àmúsgbára pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ ti wọn ni láti jẹ Nudùlù

Odi ti wọn fi waya dá ní ọgbà ẹwọn Canon City, Colorado, US.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìkòkò núdùlù jẹ ó gbóná fẹlif-fẹli lógbàẹwọn US

7. Ní orilẹ̀-èdè China, Núdùlù ń sàfihan ẹmí gígùn

Núdùlù jẹ àmì ẹmí gígùn ní China, bí núdùlù náà ba ṣe gùn tó ní ẹmi ẹni náà yóò ṣe gùn ìgbàgba àwọn China rèé.

''Núdùlù ẹmí gígùn'' èyí máa ń gùn jú núdùlù lọ, wọn máa ń dín-in tabí kí wọn bọ̀ọ́, wọn sì máa ń sábà fi ṣe ayẹyẹ ọdún túntún ní China ni.

Kìí ṣe ohun tó bá ojú mu láti gẹ núdúlù sí wẹ́wẹ́

Two Thai men making traditional Chinese style noodles in a Bangkok market Okunrinará Thai méji ti wọn ṣe Núdùlù ní ọjà Bangkok

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Tani yóò kẹ̀yìn sí Núdùlù tí máa mú ẹmi ẹni gùn tó tún máa ń fun ni àláfìà

8. Àwọn ti Korea máa ń fẹ láti ṣe Núdùlù wọn láti ara èdso igi apádò

Ní Korea onírúurú núdùlù ní wọn máa ń ṣe láti ara èso igi apádò (Oak tree)

Eso igi apádo tabi dotori guksu, ní wọn maa ń dapọ mọ àwọn eso onikóró míràn bíi wiiti lati fi ṣe núdùlù.

Awon US náa a maa lo ìyẹfun tí ó jáde lára èso igi apádò

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ohun ìwúri ni lílo èso igi apádò fún àwọn olùdáná ní Korea

9. Núdùlù to gùn jùlọ ní kìlómítà mẹ́ta lóròó

Orílẹ̀-èdè China ló gba Núdùlù tó gùn jùlọ nínú ìwé ìránti àwọn iṣẹ̀lẹ̀ málegbàgbé làgbáyé nítori wọn ni ile ounjẹ tó ń ṣe daradara lẹ̀yìn ti wọn se Núdùlù kan tó gùn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́rìn lélọ́gọ́rin míta.

Àwọn osiṣẹ Xiangnian Food Co. Ltd ló wákàti mẹ́tàdílógún láti kaa kò

Awọn ènìyàn ṣe àfihan núdùlù oní ọgọrun mẹ́tà mita ní Jiangsu China.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn aládugbò Yangzhou ní China kóra jọp;ọ̀ ní 2015 láti ṣe núdùlù tí yóò gùn tó mítà ọgọ́rùn mẹ́ta

10. Ọ̀rọ̀ tó ń jẹ́ "noodle..." orílẹ̀èdè Germany ló ti ṣẹ̀ wá

Orúkọ núdùlù (Noodle) ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ti German

Noodle word writen with noodle letters

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Spell it out

Sevaiyan, macarrao, onye onyoghonyo, erişte, mi, vermicelli, fideu, soba, spaghetti, arishta, tambi, udon, nouille, mian tiao..Oríṣi orúkọ ní wọn ń lò láti sàpèjúwe Núdùlù láti sàkàwé ǹkan gbọ̀ọrọ tó dàbí okùn.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà awọn ènìyàn máa ń fí Núdùlù pé orúkọ tó jẹyọ nínú èdè gẹ̀ẹ́sì sùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ní pé ipinlẹ̀ rẹ̀ wá láti German.

Àkọlé fídíò, Wo itan omi gbigbona ati tutu ni Ikọgosi Ekiti