Bala Bantex: Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde òní ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi nítorí ikú ìgbákejì gómìnà Bantex tó dolóògbé

El Rufai

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede isinmi lẹni iṣẹ fun gbogbo oṣiṣẹ ni ipinlẹ Kaduna loni ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu keje, ọdun 2021.

Ijọba kede isinmi yii lati bu ọla fun igbakeji gomina ana, Bala Bantex to jẹ Olorun nipe lanaa, ọjọ aiku, ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 2021.

Bala jẹ igbakeji gomina lati oṣu karun un ọdun 2015 si osu karun un, ọdun 2019 ni ipinlẹ Kaduna.

Ogbeni Muyiwa Adekeye to jẹ olubadamoran lori ifitonileti fun Gomina El Rufai to n tukọ ipinlẹ Kaduna lo fi ikede yii sita.

Atẹjade naa ni olubadamoran gomina buwọlu lẹyin ti iroyin naa ni o fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi oloogbe

O ni adura Malam Nasir El Rufai ni pe ki Oba Oke dẹ ile fun ẹni to lọ.

Bantex Bala

Oríṣun àwòrán, @Bantex

Ta ni Bala Bantex to doloogbe?

Bala Bantext jẹ igbakeji gomina to tukọ ipinlẹ Kaduna lati ọdun 2015 si ọdun 2019.

O jẹ akọṣẹmọṣe awọn to n ya ile ati ibi iṣẹ ati ibugbe nalnla.

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Gomina Nasir El Rufai lo fidi iku rẹ mulẹ lana ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla, osu keje, odun 2021.

Bala dagbere faye lẹni ọdun mẹrinlelogọta.

Gomina El Rufai ni Bala jẹ ọrẹ oun tootọ koda titi di igba ti o fi ṣaisan.

El Rufai

Oríṣun àwòrán, @EL Rufai

Bala Bantex wa lara awọn aṣoju to lọ si apero Constitutional Conference, to waye lọdun 1994.

Oun ni alaga ijọba ibilẹ Kaura to tun ṣoju ẹkun Kaura Constituency nile igbimọ aṣojuṣofin

Ọpọ ẹbi ati ọrẹ lo n ṣelede lẹyin igbakeji gomina naa, Barnabas Yusuf Bala Bantex.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua