Euro 2020 update: Italy gba ife ẹ̀yẹ lẹ́yìn tó ná England pẹ̀lú àmì ayò 3-2

Italy vs England

Oríṣun àwòrán, PAUL ELLIS

Orilẹ-ede Italy ti di ikọ agbabọọlu to pegede julọ nilẹ Yuroopu lẹyin ti wọn dana iya fun ikọ agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi pẹlu ami ayo mẹta si meji.

Adele Italy, Gianluigi Donnarumma gba ikọ rẹ silẹ lẹyin to mu bọọlu kọju simi ki n gba si ọ lati ọwọ Bukayo Saka, eyii to mu ikọ naa bori.

Ṣaaju ni ikọ mejeji ti kọkọ gba bọọlu fun ọgọfa iṣẹju ti ko si eyikeyi to bori ninu wọn, ki wọn to fi kun asiko ifẹsẹwọnsẹ naa, ti ipele bọọlu kọju simi ki n gba si ọ si tẹle.

Bukaya Saka and Harry Kane

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba keji ree ti aṣekagba ifẹsẹwọnṣe idije bọọlu ilẹ Yuroopu yoo wọ ipele bọọlu kọju simi ki n gba si ọ nitori bi ikọ memeji ṣe pari ifẹsẹwọnsẹ naa si ọmi ayo kọọkan.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ ifẹsẹwọnṣẹ naa, o jọ bi ẹni pe ikọ England yoo rọwọ mu pẹlu bi Luke Shaw ṣe kọkọ ta biọ biọ.

Ṣugbọn lẹyinorẹyin iya lo ba de fun ikọ ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti ifẹsẹwọnsẹ naa pari, ti Italy si gba ifẹ ẹyẹ pẹlu ami ayo 3-2.