Sergio Ramos transfer news: Òfófó àwọn tó ń ṣé ìdúnadúrà agbáọ́lù lágbayé

Ramos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn idunadura ti n lọ lọwọ lori awọn agbabọọlu kaakiri agbaye.

B'awọn kan ṣe n palẹmọ ati ta agbabọọlu l'awọn miran n gbero lati ra .

Diẹ ree ninu wọn lati ọdọ awọn oju iwe iroyin idaraya.

AS sport to jẹ iwe iroyin lede Spanish sọ pe Paris St-Germain , Manchester City , Manchester United ati Sevilla wa lara awọn ẹgbẹ agbabọọlu to n gbiyanju lati ra balogun ikọ Real Madrid, Sergio Ramos to ṣetan lati kuro.

Ọmọ orileede Spain yii, tii ṣe ẹni ọdun marundilogoji naa bẹrẹ ere bọọlu pẹlu Sevilla ṣugbọn lẹyin ọdun mẹrindilogun yoo fi Madrid silẹ nitori bi ọrọ ko ṣe wọ laarin rẹ ati awọn adari ẹgbẹ ọhun.

Brighton gẹgẹ bi Sky Sports ṣe t'awa lolobo ti ni awọn ko le gba ogoji miliọnu pọun ti Arsenal ko le agbabọọlu agbaarin wọn ẹni ọdun mẹtalelogun ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Ben White.

Arsenal bakan naa tun jawọ idunadura lori agbabọọlu ọmọ ilẹ Norway Martin Odegaard, lẹyin to ni oun fẹ pada si Madrid toun ti pe wọn ya lo ni Emirate fun ọpọ asiko ni saa bọọlu to pari tan yi.

Ramos

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kingsley Coman ọmọ orileede France fẹ pada si Premier League lẹyin to kọ lati buwọlu adehun mi pẹlu Bayern Munich gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin Sky Sports ṣe jabọ.

Voetbal International to jẹ iwe iroyin ere idaraya lede Dutch ni Inter Milan ati Everton yoo jijọ figagbaga lati le ra Denzel Dumfries lọwọ PSV Eindhoven.

Iwe iroyin Guardian la ti ri iroyin eleyi to ni Brighton ti gba lati san £25m fún atamatase ọmọ Argentina Nicolas Gonzalez to n ṣoju fun Stuttgart.

Goolu mẹfa lo jẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹẹdogun ni saa bọọlu 2020/2021 to kọja ni Bundesliga.

Tottenham fẹ ra atamatase ẹni ogun ọdun to n ṣoju Brighton Tariq Lamptey.

Brighton naa tun ko si idunadura pẹlu atamatase ilẹ Gẹẹsi tẹlẹ Danny Welbeck lori ibuwọlu iwe adehun tuntun (The Argus)

Erongba Harry Kane lati fi Tottenham silẹ lọ si Manchester City ti di imusẹ lẹyìn t'awọn mejeeji ti fẹnu ko lori adehun.

Inu iwe iroyin The Telegraph lọrọ yi ti jẹyọ.

Lakotan fun ẹyin ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea, La Republica to jẹ iwe iroyin ni Italy sọ pe Chelsea ti daba ọgọta miliọnu dọla pẹlu Marcos Alonso lati fi ra atamatase Inter Achraf Hakimi.

A gbọ pe Paris St-Germain naa n foju sí agbabọọlu yi lara ti wọn si fẹ ja gba mọ wọn lọwọ.