Gani Adams: Ẹ̀yin àjọ àgbáyé, ẹ dìde yanjú wàláhà Nàíjíríà kó tó dojúrú tán

Aarẹ Ọna Kakanfọ Ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti kọ lẹta si awọn ajọ agbaye, to fi mọ awọn orilẹede ilẹ okeere, lati dasi eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Ninu lẹta ti Gani Adams buwọlu fun ara rẹ, lo ti sọ fun awọn ajọ ilẹ okeere yii pe, ti wọn ko ba dasi eto aabo to dẹnukọlẹ ni ilẹ Yoruba yii, yoo ni ipa buruku lori ọrọ aje wọn lorilẹede Naijiria.
Gani Adams, to pe akọle lẹta naa ni '' Igbesẹ kanmọ n kia lati dawọ iwa isekupani awọn Fulani Darandaran duro nilẹ Yoruba" ni ohun to pọn dandan ni ki awọn orilẹede wọnyii dasi ọrọ iṣekupani ojojumọ naa.
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- Gani Adams: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ti kàn sí OPC lórí ètò ààbò
- Gbàjarè! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ agbébọn lo wà nílúù Kishi, National Park - Gani Adams figbe ta
- Gani Adams àti Seyi Makinde ṣèpàdé, àbọ̀ wọn rèé
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Ẹ̀yin Fulani, ẹ yàgò fún ilẹ̀ Yorùbá lásìkò yìí- Iba Gani Adams
- Gani Adams yarí pé èdè Yorùbá gbọdọ̀ di ọ̀rànyàn nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀
Awọn ti Gani Adams kọ lẹta naa si ni Akọwe Agba Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN, Alaga Ajọ Iṣọkan ilẹ Africa, AU, Ijọba orilẹede Amẹrika, Akọwe ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Ajọ iṣọkan Ilẹ Yuroopu ati awọn orilẹede to wa ni abẹ rẹ.
Awọn orilẹede ati Ajọ to ku ti Gani Adams tun kọ lẹta naa si ni Ajọ Economic Community of West African States (ECOWAS); orilẹede Germany, Canada, Italy, Japan, Holland, Sweden, South Africa, Ghana, Togo Benin Republic ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa ni Gani Adams bu ẹnu atẹ lu iha ti ijọba apapọ Naijiria kọ si ikọlu awọn darandaran ni ilẹ Yoruba ati bi wọn ko ṣe gbe igbesẹ kankan nipa rẹ.
''Ipaniyan ojojumọ ni Naijiria paapaa ni ilẹ Yoruba ko ni ojutu mọ, ojojumọ ni awọn Fulani darandaran n pa eniyan bi ẹran''
Ti ijọba lawọn orilẹede agbaye ko ba tete dasi iṣẹlẹ to n lọ lọwọ yii, o ṣeeṣe ki ogun abẹle ati ija ẹlẹyamẹya bẹ silẹ kaakiri orilẹede Naijiria.''
''Nibayii, ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọ Naijiria ni ko le e sun lai foya nitori ipaniyan to n waye kaakiri paapaa ilu Igangan ti wọn ti n paniyan ni ojojumọ''
Gani Adams ni o ṣe ni laanu wi pe ijọba Aarẹ Buhari fi aye gba ipaniyan yii lati tẹsiwaju pẹlu gbolohun ti wọn n sọ wi pe, ko si ẹnikẹni to le e le ẹya kan kuro ni agbegbe kan lorilẹede Naijiria.
Aarẹ Ọna Kakanfo Ilẹ Yoruba naa wa kesi awọn orilẹede lagbaye ati Ajọ naa, lati dasi ọrọ yii ki o to dojuru patapata nitori o ti su awọn eniyan, ti wọn si ti fẹ ma a gbe ohun ija lati daabo bo ara wọn.


















