Gani Adams: Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ wọ iléẹ̀kọ́ gíga nílẹ̀ Yorùbá gbọdọ̀ yege nínú èdè abínibí

Oríṣun àwòrán, Nigerian Canadian agency
Aarẹ Ọna kakanfo tilẹ Yoruba, Gani Adams ti kesi awọn gomina to wa lawọn ipinlẹ mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba lati sọ ẹkọ ede Yoruba di ọranyan.
Ede Yoruba yii ni Adams ni o gbọdọ jẹ dandan fawọn akẹkọọ lati yege ninu rẹ, ki wọn to le gba wọn wọle sawọn ile ẹkọ giga to jẹ tawọn ipinlẹ nilẹ Yoruba.
Aarẹ Ọna Kakanfo ni igbesẹ yii ni yoo daabo bo ede abinibi wa ko ma lọ sokun igbagbe laipe ọjọ.
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Ẹ wo àwòrán bí Sunday Igboho ṣe ṣàbẹ̀wò sí Aarẹ Gani Adams nílé rẹ̀ nílùú Eko
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
- Ẹyọ kan lára agbára tí mo ní, ni mo lò láti mú Wakili - Gani Adams
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Wakili ti gba òmìnira lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Iyakangu
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
- Ìdí tí mi ò fi lè parí ìjà pẹ̀lú Ààrẹ Ọ̀nà kakanfò, Gani Adams - Obasanjo
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo fèsì sí ẹ̀ṣùn Aláàfin àti Gani Adams pé ó ń tú afurasí sílẹ̀
Aarẹ Gani Adams gbe imọran yii kalẹ lasiko ajọdun asa ibilẹ to maa n waye lọdọọdun nipinlẹ Oyo eyi ti wọn pe ni Ọdun asa ibilẹ fun igbafẹ ti Omi tuntun.
Ọdun ibilẹ naa, ti wọn pe akori rẹ ni 'Asa wa...Ipilẹ wa' nileesẹ eto iroyin, asa ati igbafẹ nipinlẹ Oyo se agbatẹru rẹ eyi to waye ni gbọngan asa ibilẹ, loke Mokola nilu Ibadan.
Aarẹ Gani Adams fikun pe asa ni nnkan se pẹlu asọ ti ẹya kan ba n wọ, ede ti wọn n sọ lẹnu ati ọpọ ohun to nii se pẹlu ẹya naa.
"Gẹgẹ ba se n mu ede Gẹẹsi ati isiro lawọn ile ẹkọ ni ọranyan, naa lo yẹ ka fi ede Yoruba se ọranyan ki akẹkọọ to wọle ẹkọ giga lawọn ipinlẹ.
Eyi yoo sewuri fawọn akẹkọọ iran yii lati mọ ede abinibi wa lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama, ki wọn to ri aaye wọle ẹkọ giga.
Koko ohun to yẹ ka fi sinu ilana eto ẹkọ ree, ede Yoruba gbọdọ jẹ dandan ninu rẹ, awọn olukọ to n kọ ede Yoruba kan si gbọdọ mu isẹ wọn lọkunkundun pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
Gani Adams wa gbawọn gomina ipinlẹ nilẹ Yoruba lati bẹrẹ si ni gba awọn olukọ ede Yoruba sisẹ lati se iwuri fawọn ogo wẹẹrẹ ati ọdọ wa.
O fikun pe awọn obi ko ni akoko to pọ lati lo pẹlu ọmọ ninu ile,ọpọ iwa tawọn ọmọ wa si n hu ni wsn kọ lati ọdọ awọn ọdọ wọn.
"Mo wa n rọ awọn gomina wa lati sọ ede Yoruba di ọranyan fun gbogbo akẹkọọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ gigalaarin ọdun mẹta si akoko yii."


















