Obasanjo: Mo lòdì sí ìgbé ayé tí Gani Adams ń gbé látẹ̀yìnwá, ṣùgbọ́n n kò bá a jà - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Eagleonline
Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ni ko si idi fun oun lati pari ija pẹlu Aarẹ ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams.
Oloye Ọbasanjọ ni idi ni pe ko si igba kan yala latẹyinwa tabi nisinyi ti ija wa laarin oun ati Iba Gani Adams, nitori naa ko si idi lati maa pari ija ti ko si.
Ninu atẹjade kan eyi ti amugbalẹgbẹ fun Oloye Ọbasanjọ lori ọrọ iroyin, Kẹhinde Akinyẹmi fi sita lọrọ yii ti jẹyọ.
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Ìwé àkàgbádùn láti ọwọ́ Fagunwa, Faleti, Iṣọla, Ogunniran àti Okediji tó yẹ kí o kà lásìkò yìí...
- Ọwọ́ wa ti tẹ àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Olufon ti Ifon, Oba Israel Adeusi - Amotekun
- Wo bí ìlànà tuntun lórí gbígba físà UK lẹyìn Brexit ṣe kàn ọ́
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ti Pfizer ṣe yóò di lílò láti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀
Aarẹ Ọbasanjọ ṣalaye pe sababi ni ipade oun ati Iba Gani Adams ni ile agba ilẹ Yoruba to tun jẹ aṣiwaju ẹgbẹ Afẹnifẹre ni agbegbe Lekki Phase 1 jẹ, kii ṣe lati pari ija kankan.
Aarẹ ana naa ṣalaye pe ko si ohun meji ti oun ni tako aarẹ ọna kakanfo ilẹ Yoruba naa ju igbe aye rẹ atẹyinwa lọ ti ko ba iṣe oun mu.
Gbogbo ibeere Gani Adams lati bẹ oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ wo yala nigba to wa nipo gẹgẹ bi aarẹ ati lẹyin to fi ipo silẹ ni oloye Ọbasanjọ kọ.
Oloye Ọbasanjọ ṣalaye ninu atẹjade naa pe, 'Lootọ ni mo bẹ Oloye Ayọ Adebanjọ wo ni ile rẹ to wa ni agbegbe Lekki Phase 1 ni ọjọ keji oṣu Kejila ọdun 2020 ti mo si pa Gani Adams nibẹ'.
"Mi o ni ija tabi aawọ kankan bi o ti wulẹ o mọ pẹlu Gani Adams, ṣugbọn igbe aye rẹ atẹyinwa ti ko ba irinajo mi mu ni mo tako"
"Bi ẹnikẹni ba lero pe mo ni aawọ pẹlu oun to nilo ka pari, irufẹ ipari ija bẹẹ ko lee waye nibomiran yatọ si ile mi ni Abẹokuta."

















