Olufon of Ifon: Ọwọ́ àwọn òṣìṣẹ́ alààbò tẹ àwọn afurasí tó pa Oba Israel Adeusi ní ìpínlẹ̀ Ondo

Oríṣun àwòrán, The Newstrack
Ọwọ ti tẹ awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu iku Olufon ti ilu Ifon, ni ipinlẹ Ondo, Oba Israel Adeusi.
Iroyin ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa lẹyin ti awọn oṣiṣẹ eto abo ya bo inu igbo Ẹgbẹgbẹka, nibi ti wọn gbagbọ pe awọn afura naa farapamọ si.
Adari ikọ Amotekun ni ipinlẹ Ondo, Adeleye Olusanyero sọ fun BBC pe "ootọ ni, a ti mu awọn afurasi kan ti a gbagbọ pe wọn lọwọ ninu iku Olufon."
Adeleye tẹsiwaju pe "gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe ile ẹjọ nikan lo le sọ boya eeyan jẹbi ẹsunkẹsun, ṣugbọn ootọ ni pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi kan."

Oríṣun àwòrán, Amotekun
Adari ikọ Amotekun naa tun ṣalaye pe ikọ ọhun ti doola ẹmi awọn eeyan mẹrin ti awọn afurasi naa ji gbe.
Ọsẹ to kọja ni awọn afurasi ajinigbe naa pa Ọba Adeusi ni Elegbaka, lasiko to n pada si ilu rẹ lẹyin ipade igbimọ lọba lọba to lọ fun niluu Akure.
Ajọsepọ àwọn ileesẹ alaabo to yabo inu igbo Elegbaka, lẹyin iku ọba naa, lo ṣokùnfà bi ọwọ ṣe tẹ wọn.
Lọwọ-lọwọ, o ni iwadii ti n lọ lori awọn afurasi ti ọwọ tẹ.













