Stella Obasanjo Motherless: A ti rí àwọn ọmọ tó sọnù ní ilé àwọn ọmọ òrukàn ní Abeokuta

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi/Facebook
Nigba ti BBC Yoruba kọkọ kan si ọlọpaa ipinlẹ Ogun, agbẹnusọ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi sọ fun wa pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ awọn ọmọ naa to si kọ lati pese ẹkunrẹrẹ.
Kete lẹyin eyi la kan si ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin. Kọmisọna ileeṣẹ yii lo tu kẹkẹ ọrọ kalẹ to si ṣalaye bi gbogbo nkan ṣe ri gan.

Oríṣun àwòrán, Olamide Lawal/Facebook
Ọmọ 28 lapapọlo di awati
Kọmisọna fun ọrọ awọn obinrin ni ipinlẹ Ogun, arabinrin Funmi Efuwape ni lati ijẹta ni awọn ọlọpaa ti ri awọn ọmọ marun eyi ti awọn oniroyin n gbe kiri pe wọn di awati nile ọmọ orukan Stella Obasanjo Motherless Homes niluu Abeokuta.
Funmi ṣalaye wipe o ni ileeṣẹ foyungbawo kan (Baby Factory) ni awọn ọmọ naa salọ pada nibi to jẹ wipe awọn ti kọkọ ri wọn.
"Arabinrin to lo wọn fi ṣowo ọmọ bibi lo ko wọn lọ si ibomiran ti ẹnikankan ko mọ".
Nipa oludari Ileeṣẹ Foyungbowo yii
Arabinrin Funmi sọ fun BBC Yoruba wipe ninu oṣu keji ọdun 2020 ni awọn ti gbọ finrin pe ileeṣẹ foyungbowo kan wa nipinlẹ Ogun ti Ọlọpaa si lọ.
"Wọn ko gbogbo awọn ọmọbinrin naa, ọlọpaa si rọ wa lati wa ibugbe fun, a gba la fi ko wọn sile awọn ọmọ orukan Stella Obasanjo".
Funmi ni awọn kọ wọn bi wọn ṣe n ṣe oriṣiriṣi nkan ipanu atawọn iṣẹ ọwọ mii. "Amọ a ni lati gbọ lati ile ẹjọ lori ọrọ wọn ki a to le da wọn pada saarin ilu lati di oniṣẹ ara wọn".
ẹwẹ, o ṣalaye wipe o jọ bii pe obinrin to ni ileeṣẹ foyungbowo ọhun ni nọmba wọn lọwọ lo ṣe ri wọn pe pada ti awọn ọmọ naa fi salọ sọdọ rẹ.
"Obinrin naa ni tirẹ n fẹ lati ta awọn ọmọ ti wọn ti bi eyi si lodi si imọran ati ẹkọ ti a n gba wọn".
Ọmọ márùn ún di àwátí ní ilé àwọn ọmọ òrukàn, Stella Obasanjo Motherless Home ní Abeokuta
Awọn ọmọde marun un ti di awati ni ileegbe awọn ọmọ orukan, Stella Obasanjo Motherless Children's Home to wa ni Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
Iroyin ni awọn ọmọ naa ti di awati lati Ọjọbọ, oṣẹ to kọja ti wọn ko si tii ri wọn titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Ijọba ipinlẹ Ogun ninu ọrọ wọn ni awọn ti fi to ọlọpaa leti pe ọmọ marun un ti di awati ni ile ibugbe awọn ọmọ orukan naa.
- Oluwatobi Adeigba, Ọkọ mi ń lọ siṣẹ́ fún àjọ INEC ló kàgbákò ikú - Opó Adeigba
- Ìdí tí a fi pa àwọn àgbẹ̀ onírẹ̀sì ní Borno, Boko Haram ṣàlàyé nínú fídíò tuntun
- Èèyàn 281 ló kó covid-19 lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, 123 wá láti ìpínlẹ̀ Eko nìkan
- Wọ́n ti rẹ ipò ọ̀gágun Olusegun Adeniyi sílẹ̀ lẹ́yìn tó jẹ̀bi títú àṣírí kùdiẹ-kudiẹ iléeṣẹ́ ológun lórí ayélujára
Kọmisọnna fun eto iroyin, Abdulwaheed Odusile sọ wi pe ijọba ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, nitori awọn ti fi to ọlọpaa leti.
Odusile fikun wi pe awọn ọmọ to wa nibi ile ibugbe awọn ọmọ orukan naa wa ni abẹ aabo to daju nitori gbogbo wiwọle-jade wọn ni awọn n tọpasẹ rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, ijọba ti gbe igbesẹ lati ri wi pe awọn ọmọ naa pada wale.
''Ijọba gomina Dapo Abiodun ti kọwe si gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ati awọn ẹṣọ aabo lati ri wi pe otitọ jọba.
Bakan naa ni ijọba ni ki awọn araalu fọkanbalẹ nitori otitọ ni yoo jọba ninu iṣẹlẹ yii, ati wipe awọn ọmọ naa yoo di awari, ti wọn yoo si pada sile ni ayọ ati Alaafia.
















