Alaafin Oyo: Olorì Anuoluwapo Adeyemi gba àmì ẹ̀yẹ lórí oge ṣíṣe

Olori

Oríṣun àwòrán, Royal Image Photography

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aya Alaafin ilu Oyo tẹlẹ, Olori Anuoluwapo ti kede pe wọn ti fun oun ni ami ẹyẹ fun ipa ti oun ko nipa eto oge ṣiṣe.

Olori Anuoluwapo lo kede bẹẹ loju opo Instagram rẹ lọsan ọjọ Aje.

Nigba to n kede ami ẹyẹ naa, o ni "mo ki gbogbo wa ku oriire o, ami ẹyẹ yii wa fun gbogbo awọn ẹbi mi loju opo Instagram yii nitori mi o jẹ ohun kankan laisi Ọlọrun ati ẹyin ololufẹ mi."

Àkọlé fídíò, Kí ni "Present tense" lédè Yorùbá?

Ileeṣẹ iroyin City People lo fun Anuoluwapo ni ami ẹyẹ ọhun lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2020.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Anuolouwapo jẹ ọkan lara awọn Olori Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi III, eyii ti awọn eeyan kan gbagbọ pe oun ni aayo Kabiesi.

Ṣugbọn ni nnkan bi oṣu diẹ sẹyin ni iroyin gbode pe Olori naa ti ko kuro ni aafin Iku Baba Yeye.

Ṣaaju akoko naa ni iroyin ti kọkọ gbode pe họwuhọwu n waye laarin Kabiesi ati Olori yii lẹyin ti awọn kan fẹsun kan Olori ọhun pe o ni ibaṣepọ pẹlu gbajugbaja Olorin fuji kan.

Ṣugbọn Olori Anuoluwapo ati olorin fuji naa ti sọ pe ahesọ lasan ni, nitori ko si ohun to jọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára

Olorì Anu ni Ọba Adeyemi ń halẹ̀ máwọ̀n ẹbí òun torí kò mọ ibi tí òun wà

Olori Anuoluwapo Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen__aanu

Yoruba ni ba ba dakẹ, tara ẹni maa n bani dakẹ ni, igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere si la tii lọ ọ.

Eyi lo mu ki aayo Alaafin tilu Oyo tẹlẹ, Olori Anu fi n kigbe gbami-gbami fun araye nipa awọn ewu to ni oun n la kọja.

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin nipa ikede ti Olori naa gbe soju opo Twitter rẹ, nibi to ti pariwo pe ẹmi oun si wa ninu ewu tori pe oun kọ Alaafin.

Olori Anu, ninu igbe to fi bọnu naa, tun tẹsiwaju pe a kii dakẹ ku, ẹnikan kii si wo sun daran, idi si ree ti oun ko fi ni panumọ nitori ewu to n rọ dẹdẹ lori oun.

Olori Anuoluwapo Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen__aanu

"Mo n pariwo sita lati daabo bo ẹmi mi ni nitori ko yẹ ki idunkooko mọ ẹmi mi wa tori pe mo ko kuro ninu Aafi

N ko le di awọn ọmọ mi lọwọ lati mọ baba wọn laelae, amọ gẹgẹ bi iya, oun to tọ fun mi ni lati ko wọn sọdọ mi."

Olori Anu wa kere pe ẹnu ya oun lati sawari rẹ pe wọn n yaju sawọn mọlẹbi oun nitori pe alaafin ko mọ ibi ti oun wa.

Bakan naa lo tun fi kun pe, gbogbo igbiyanju lati ji oun gbe lo ja si pabo, idi si ree ti oun ko fi le panumọ rara mọ, o ti to gẹ.

Olori Anuoluwapo Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen__aanu

"Mo kọ lati maa gbe ninu igbekun, maa si sa gbogbo ipa mi gẹgẹ bo se wa labẹ ẹtọ ti mo ni lati wa ni ominira. Mo fẹ gbe ile aye lati se iya awọn ọmọ mi."

Olori Anu ni oun n lo anfaani ikede naa lati tọrọ aforijin lọwọ ẹnikẹni ti oun ba ti ja kulẹ tabi to n binu si oun nitori ikede naa.

"O di dandan ki n pariwo sita ni nitori ẹmi mi ko de mọ. Ẹmi mi se pataki si mi. Mo si fẹ maa rin, maa yan kiri lati bẹru pe ẹnikẹni n sọ mi kiri.

Alaafin Oyo: Olorì Anu ni ẹ̀mí òun wà nínú ewu tori òun kó kúrò ní ààfin

Oríṣun àwòrán, Queen_Aanu/Instagram

Bakan naa ni n ko fẹ maa bẹru lori pe ohunkohun to jẹ aburu le sẹlẹ si mi."

Olori Anu naa wa pari ọrọ rẹ pe oun dupẹ pe ẹ fi oye gbe alaye oun.

Bí nǹkan bá ṣe mí àtàwọn ọmọ mi, Aláàfin ni kẹ mú o - Olorì Anu figbe ta

Olori Anuoluwapo Adeyemi

Oríṣun àwòrán, Instagram/queen__aanu

Saaju la ti sọ fun yin pe, Olori Anu ti bọ soju opo Instagram ni irọlẹ Ọjọru lati kede fun araye pe oun ti kuro ninu aafin.

Anu, ẹni to ni pẹlu ibanujẹ ni oun fi n kọ ikede naa tun ni ó pọn dandan lati ṣe bẹẹ nitori ẹ̀mí oun atawọn ọmọ oun wa ninu ewu.

Olori naa, to bi ibeji fun Alaafin wa kede fun araye pe bi ijamba kankan ba ṣe oun atawọn ọmọ oun, Alaafin ni kí wọn mu.

O ni nitori pe oun kuro ninu igbeyawo oun ni wọn ṣe n dunkooko mọ ẹ̀mí oun, oun si wa n pariwo pe, Alaafin lo wa nidi rẹ, bi ibi ba sẹlẹ si òun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Kii ṣe ifẹ ọkan mi lati da igbeyawo mi ru lainidi, n ko si le tẹsiwaju mọ lati maa gbe ninu igbekun.

Alaafin Oyo: Olorì Anu ni ẹ̀mí òun wà nínú ewu tori òun kó kúrò ní ààfin

Oríṣun àwòrán, @queen_anu

O wu emi naa lati lati gbe ile aye bo ṣe yẹ, ki n si jẹ iya rere to dara julọ fun awọn ọmọ mi."

Olori Anu ni oun kọ lati ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ nitori ọrọ asiri aye oun ni eyi jẹ, ati fun aabo awọn ọmọ oun.

Olori naa ni oun pinnu lati rọra kuro ninu aafin lai pariwo, ki oun le wa nile aye lati ṣe iya awọn ọmọ oun ni.

Amọ o ni o da oun loju pe ẹ̀mí oun wa ninu ewu, idi si ree ti oun fi kuro ninu igbeyawo oun, amọ oun ko ni panumọ nipa rẹ.

Alaafin Oyo: Olorì Anu ni ẹ̀mí òun wà nínú ewu tori òun kó kúrò ní ààfin

Oríṣun àwòrán, Queen_Aanu/Instagram

"Mo mọ pe awọn eeyan ti ni ero wọn nípa mi, boya o tọ tabi ko tọ, lori idi ti mo fi fẹ ọba alaye naa tabi kuro ninu igbeyawo ọhun.

Lai sọ̀rọ̀ pupọ, mo fẹ kẹ wa wọ bata ti mo bọ silẹ wo, ẹ ki ẹsẹ bọ wo, kẹ le mọ bo ṣe ri ati bo ṣe n ta mi lẹsẹ si, kẹ to maa da mi lẹjọ."

Olori Anu ni kii ṣe pe oun n fẹ kawon eeyan kanu oun, ni oun ṣe fi ikede naa sita àmọ́ oun kan fẹ ko wa ni akọsilẹ ni.