Coronavirus Update in Nigeria: 'Ẹ sọ́ra fún "Christmas Carol", ẹ̀yin tẹ́ẹ sì wà lókè òkun ẹ má wálé o!'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati ṣọra fun apejọpọ lasiko ọdun keresimesi to n bọ yii nitori ajakalẹ arun Coronavirus.
Adari ajọ pajawiri ti aarẹ Buhari gbe kalẹ lati tako aarun Coronavirus, Boss Mustapha lo sọ bẹẹ fun awọn oniroyin ni Abuja.
Mustapha ni ki awọn eniyan ma rin irinajo lọ si oke okun lasiko yii ti ko ba pọn dandan lati rin irinajo.
- Akomolede ati Asa Yoruba: Kí ni "Present tense" lédè Yorùbá?
- Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ oṣù tí òjò kò rọ̀ ní orílẹ̀èdè Cuba, Ọba ilẹ̀ Yorùbá ló pàṣẹ kí òjò rọ̀ níbẹ́ tó sì rọ̀-Elebuibon
- Olorì Aláàfín tẹ́lẹ̀, Anuoluwapo Adeyemi gba àmì ẹ̀yẹ lórí ipa tó kó nínú oge ṣíṣe
- Ṣé àwọn ìjayà ajaguntà ilẹ̀ òkèrè leè bá Nàìjíríà fòpin sí ìṣòro àbò?
- Awakọ̀ agbókùú, ọlọ́pàá, ológun, oníròyìn ló máa ń kọ́kọ́ dìbò ní Ghana, bó ṣe ń lọ rèé
Bakan naa ni wọn rọ awọn ọmọ Naijiria to wa ni oke okun lati duro sọhun ki wọn ma wale lasiko yii nitori ajakalẹ arun Coronavirus.
''Fun ilera ara yin ni a ṣe n parọwa si yin lati maṣe rin irinajo lasiko yii nitori ajakalẹ arun Coronavirus''.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
''Ipejọ lasiko ọdun Keresi ko pọn dandan, bẹẹ si ni ko si ni 'Christmas Carol' ki awọn eniyan ma lo kọ arun Coronavirus.''
Lori ipese abẹrẹ ajẹsara lati gbogun ti arun Coronavirus, ijọba ni awọn ṣiṣẹ lori rẹ, ati wi pe yoo wa fun awọn araalu laipẹ.
Bakan naa ni wọn parọwa si awọn ọmọ Naijiria lati tẹlẹ ofin ijinasiraẹni ati fifọ ọwọ wọn loore-koore lati dẹna itankalẹ arun Coronavirus ohun.
Nibayii, esi ayẹwo Coronavirus lati ipinlẹ mẹjọ ti ajọ NCDC fi sita ni Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, fihan pe, eeyan marundinlaadọjọ tun ti ni aarun naa ni Naijiria.
Ẹgbẹrun mẹtadinlaadọrin o le ọtalelẹdẹgbẹta o din mẹta (67,557) eeyan lo ti ko aarun naa lorilẹede Naijiria lati igba ti wọn ti kẹẹfin ẹni akọkọ to laarun naa ni Naijiria ni oṣu keji ọdun 2020.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹrun mẹtalelọgọta ati ọrinlelugba ati meji (63,282) lawọn ti ara wọn ti ya nigbati aarun naa si ti gbẹmi awọn ẹgbẹrun kan ati mejilelaadọjọ (1173) eeyan.















