Adewale Adeyemo: Wally ọmọ Yoruba ni igbákejì mínísítà ìsúná ní ilẹ̀ Amẹrika ní sáà ijọba Joe Biden

Adewale Adeyemo

Oríṣun àwòrán, WALLY ADEYEMO/TWITTER

Ile igbimọ aṣofin ilẹ Amẹrika ti fi ontẹ lu iyansipo Wally Adeyemo gẹgẹ bi igbakeji adari ni ẹka eto isuna orilẹede naa eyi to jẹ ko di alawọdudu.

Ẹni to jẹ akọwe gangan, Janet Yellen lo ki ẹni ti ile aṣofin yan ku abọ - ẹni to jẹ ọga ninu imọ kikun nipa ọrọ aje ti yoo ran Amẹrika lọwọ lati di ipo agbara yii mu.

Adeyemo to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogoji naa ti ṣeleri lati mu ojutu ba "ilana ọrọ aje ti ko baramu" to n waye lorilẹede China pe oun yoo si ri i pe ofin agbaye de e.

Àkọlé fídíò, Báa ṣe lọ́pọlọ tó, ẹnu Yorùbá ò kò, ọgbọ́n táa gbúdọ̀ dá rèé - Ìpàdé àgbààgbà Yorùbá n'Ibadan
Àkọlé fídíò, 'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Joe Biden lo yan ọmọ Naijiria naa, Adewale Adeyẹmọ gẹgẹ bii igbakeji minisita fun iṣuna lorilẹede naa.

Bakan naa lo tun yan olori tẹlẹ fun banki apapọ orilẹede Amẹrika, Janet Yellen gẹgẹ bii minisita iṣuna.

Ileeṣẹ iroyin agbaye ni AFP ṣalaye pe Adeyẹmọ, to figba kan ri jẹ igbakeji alakoso eto abo lorilẹede Amẹrika, ṣugbọn to jẹ alakoso ajọ aṣeranwọ, Obama Foundation bayii ni yoo jẹ alawọdudu akọkọ ti yo di ipo naa mu, bẹẹni Yellen to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọrin ni obinrin akọkọ ti yoo di ipo naa mu.

Àkọlé fídíò, 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Ilu Adewale nilẹ Yoruba

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Tribune ṣe royin rẹ pe awọn ni gbolohun pẹlu rẹ ati leyi ti wọn si fi ṣe ibwo si ilu to ti wa.

Iwadii wn fihan pe ọmọ ilu Gbọngan ni ijọba ibilẹ Ayedaade nipinlẹ Osun ni Olawale Adeyemo. Ilu yii si wa laarin opopona Ibadan si Ile Ife.

Nibẹ ni wọn ti sọ itan nipa baba-baba Wale ati baba-baba-baba rẹ ti ọpọlọpọ mọ si 'Baba Ghana' ni ilu naa.

Agbẹjọrọ Adewale Adeyemo ni o ṣiṣẹ gẹgẹ bi olubadamọran lori eto ọrọ aje lagbaye lasiko ti aarẹ Barack Obama wa ni ipo.

Bẹẹ si ni ileeṣẹ iroyin nilẹ Amerika ni o ṣeeṣe ki o jẹ igbakeji akọwe akapo lorilẹede Amẹrika.

Adeyemo yoo ma ṣiṣẹ pọ pẹlu Arabinrin Janet Yellen ti yoo jẹ adari ẹka akapo owo lorilẹede Amẹrika labẹ iṣejọba Joe Biden.

Adeyemọ wa lara awọn eniyan jankanjankan ti awọn eniyan n reti ki aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ọhun, Joe Biden kede gẹgẹ bi awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ ni iṣejọba rẹ.

Àkọlé fídíò, Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye

Tani ọmọ Yoruba, Adewale Adeyemo tí yóò jẹ igbákejì akọ̀wé akápò ní ilẹ̀ Amẹrika?

Orilẹede Naijiria ni wọn ti bi Adewale Adeyemo ti wọn n pe ni ''Wally'' lọdun 1981, amọ ipinlẹ California, lorilẹede Amẹrika lo ti dagba.

Ileewe giga California lo ti gba iwe eri alakọkọ, ki o to lọ si ile ẹkọ imọ ofin ni Yale Law School.

Ki Adeyemo to ṣiṣẹ pẹlu ijọba aarẹ tẹlẹri Barack Obama, lo ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olootu iṣẹ akanṣe Hamilton, to si tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi igbakeji adari oṣiṣẹ ni ẹka akapo owo lorilẹede naa.

Lẹyin eyi lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari iduna dunra ikọ adehunTrans-Pacific Partnership, to si tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari oṣiṣẹ ni ileeṣẹ Consumer Financial Protection Bureau, labẹ isakoso Elizabeth Warren.

Ni ọdun 2015 ni Barack Obama yan an lati ṣiṣẹ ni ipo igbakeji oludamọran lori eto abo fun ẹka idokowo lagbaye ati igbakeji adari ajo to n risi ọrọ aje lorilẹede Amerika.

O tun ti jẹ aarẹ akọkọ fun ajọ iranwọ aarẹ Barack Obama, iyẹn Obama Foundation.