Zahra Bayero yóò di aya Yusuf Buhari láìpẹ́... ohun tí a mọ̀ rèé

Yusuf Buhari and Zahra wan marry

Oríṣun àwòrán, Yusuf Buhari/Faceboo and Daily Nigerian

Iroyin kan ti n milẹ titi lori ayelujara pe ọkanlawọn Aarẹ Muhammadu Buhari, Yusuf, ti n mura lati gbe ọmọ Emir Bichi, ni ilu Kano, Zahra Nasir Bayero ni iyawo.

Gẹgẹ bii awọn iroyin naa ṣe sọ, mọmi-n-mọọ ẹbi Aarẹ ati mọlẹbi Bayero yoo waye laipẹ, paapaa ni bayii ti iyawo Aarẹ, Aisha Buhari ti pada de si Najiria lati ilu Dubai.

Ẹnikan to sun mọ baba omidan ti wọn ni ọmọ Aarẹ fẹ gbe niyawo ọhun sọ fun BBC pe lootọ ni ọrọ ifẹ wa laarin Yusuf Buhari ati Zahra Bayero.

Àkọlé fídíò, Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ololufẹ mejeji pade lasiko ti Yusuf n kawe ni fasiti Surrey, nilẹ Gẹẹsi, eyii to jẹ fasiti kan naa ti Zahra ti kẹkọọ gboye nipa imọ aworan ile kikọ.

O ni "ootọ ni pe Yusuf Buhari ati Zahra Bayero to jẹ ọmọ Emir Bichi n fẹ ara wọn, fasiti ni wọn si ti pade."

"Bo tilẹ jẹ pe ẹbi awọn mejeji mọ si ere ifẹ wọn, ẹbi mejeji ko tii ṣe ipade kankan to jọ mọ mọmi-n-mọọ gẹgẹ bii iroyin to n lọ ni igboro, ṣugbọn awọn eeyan ninu ẹbi memeji lo n reti ki eto naa waye."

Zahra Bayero yii, yatọ si pe oun ni ọmọ Emir Bayero to jẹ alaga fun ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ 9mobile, oun tun ni ọmọ-ọmọ Emir ilu Kano tẹlẹ, oloogbe Ado bayero.

Ti igbeyawo laarin Yusuf ati Zahra naa ba waye, yoo di igba kẹta ti Aarẹ Buhari yoo ṣe igbeyawo fun ọmọ rẹ lasiko rẹ lori oye gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria.

Àkọlé fídíò, 'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

Akọkọ ni igba ti Zahra Buhari fẹ ọmọ baba olowo, Ahmed Indimi lọdun 2016.

Lẹyin naa ni Hanan Buhari, to jẹ abikẹyin Aarẹ di aya Turad Sha'aban to wa lati ipinlẹ Kaduna.

Yusuf Buhari yii ni ori ko yọ ninu ijamba alupupu lọdun 2017.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé