Kò sí ìjà kankan láàrí Ààrẹ Muhammadu Buahri àti Bolam Tinubu - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters
Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti gbe aadọta miliọnu naira kalẹ fun awọn oniṣowo ti ṣọọbu wọn jona ni ipinlẹ Katsina.
Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe Tinubu bẹ ipinlẹ naa wo laarọ Ọjọru, nibi to ti parọwa si awọn oniṣowo naa lati maṣe ba ọkan jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.
Ọpọ ọja lo jona ninu iṣẹlẹ naa, eyii to mu ki ijọba ipinlẹ ọhun gbe iwadii dide lati mọ ohun to ṣokunfa ina naa.
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba gbogbo owó táa rí kó jọ àwọn ajínigbé tún lu Kábíyèsí bí ẹni lu bàrà - Olori Oba Imope
- Iya Awero fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún níbí tó ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun
- Ìdí rèé ti mo fi gbé àfẹ́sọ́nà ẹ̀gbọ́n mi níyàwó lẹ́yìn ikú rẹ̀
- Orúkọ àwọn 10 tó pàdánù ẹ̀mí wọ́n nínú ìyibọ́npanìyàn ilé ìtajà ìgbàlódé réè
Ẹwẹ, ọọfisi Aarẹ Naijiria ti sọ pe ko si ija kankan laarin Aarẹ Muhammadu Buhari ati adari gbogbogbo fun ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Aarẹ Buhari, Garba Shehu fi lede, o ni irọ lasan ni awọn iroyin kan to sọ pe ija wa laarin Buhari ati Tinubu.

Oríṣun àwòrán, @SalihuAmumini
Atẹjade naa ni "ọọfisi Aarẹ fẹ fi da awọn eeyan loju pe ko si ija kankan laarin Bola Tinubu ati Aarẹ."
"Alafo diẹ to wa laarin awọn mejeji ko ṣeyin pe Tinubu kii ṣe ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ Aarẹ."
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ahesọ ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti Tinubu ko ṣabẹwo si Aarẹ fun saa kan ṣugbọn eyii ko tumọ si pe ija wa laarin wọn.
O ni Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ APC n ṣiṣẹ takuntakun ki alaafia ati idagbasoke le wa ni Naijiria.
- Ìdìbò ọdún 2023 leè má wáyé bí ìjọba kò bá yanjú ìpèníjà ààbò - Akeredolu
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
- Ẹnikẹ́ni tó bá fa wàhálà míì lẹ́yìn rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ Hijab tó wáyé n'Ilorin yóò fojú winá òfin - AbdulRazaq
- "Afòjúsùn ẹgbẹ́ òsèlú APC ni láti ṣèjọba Naijiria fún ọdún méjìlélọ́gbọ̀n"
O tẹsiwaju pe akitiyan Aarẹ Buhari lati gbogun ti iwa ajẹbanu yoo tẹsiwaju lai fi ti ahẹsọ ọrọ ti awọn madaru kan n gbe kiri ṣe.
Shehu ni Aarẹ Buhari ati Bola Tinubu jẹ ọkan gboogi lara awọn oloṣelu ti awọn eeyan bu iyi fun ju ni Naijiria.
O ni Tinubu jẹ òpó kan pataki to jẹ ki ẹgbẹ oṣelu APC di igi araba nla ni Naijiria, nitori naa, mimi kan ko le mi ibasẹpọ rẹ pẹlu Aarẹ.
O pari rẹ pe bo tilẹ jẹ pe Tinubu kii ṣabẹwo si Aarẹ loorekoore, ibaṣepọ awọn mejeji dan mọran.
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- Èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti náwó yàlàyòlò lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ìjọba lè gbà tojú bọ owó rẹ rèé
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- Mo gbàdúrà kí n má kábàmọ́ fífagilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìbejì mi gbé nílé ẹjọ́ - Akeugbagold
- 'Ohun táá ṣe rèé bẹ́ẹ bá kọ̀ láti wá gbé àwọn òkú yín kúrò ní Mọ́ṣúárì wa'














