Colorado Shooting: Wo orúkọ àwọn èèyàn mẹ́wàá tó pàdánù ẹ̀mí wọ́n nínú ìyibọ́npanìyàn ilé ìtajà ìgbàlódé

Aworan iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan Colorado

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ilu Boulder ni ipinlẹ Colorado lAmẹrika ti gbe orukọ awọn to padanu ẹmi wọn ninu iyinbọnpaniyan to waye nibẹ.

Ninu awọn eeyan mẹwaa naa la ti ri awọn ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati bi ogun ọdun si marunlelọgọta.

Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ, awọn ọlọpaa ko ti sọ idi ti rakunrin naa fi ṣina ibọn bo awọn oluraja nile itaja naa.

Wọn sọ pe o n koju ẹsun onipele mẹwaa lori iṣẹlẹ ipaniyan yi.

Iṣẹlẹ yi n waye lẹyin ọsẹ kan ti eeyan kan pa eeyan mẹjọ to fi mọ awọn obinrin ilẹ Asia mẹfa kan ni Atlanta.

Orukọ afurasi ti awọn ọlọpaa mu ni ẹni to yinbọn pa awọn eeyan ni Ahmad Al Aliwi Al Issa ẹni ọdun mọkanlelogun.

Aworan iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan Colorado

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aṣoju agbẹjọro agba orileede Amẹrika Micheal Dougherty sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju.

Lọjọ Aje awọn alaṣẹ sọ pe iwadii naa ko le gba wọn ju ọjọ marun un lati pari.

Orukọ awọn to faragbọta ninu iṣẹlẹ naa?

Orukọ wọn ree:

Denny Stong, 20

Neven Stanisic, 23

Rikki Olds, 25

Tralona Bartkowiak, 49

Suzanne Fountain, 59

Teri Leiker, 51

Eric Talley, 51

Kevin Mahoney, 61

Lynn Murray, 62

Jody Waters, 65

Aworan iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan Colorado

Oríṣun àwòrán, Empics

Agbébọn yabo ílé ìtajà ìgbàlódé, èèyàn mẹ́wàá bá d'èrò ọ̀run

Eeyan mẹwa to fi mọ ọlọpaa kan ti kan agbako iku lọwọ agbebọn kan lẹyin ọpọ wakati to ṣina ibọn fawọn oluraja nile itaja nla kan ni Colorado, Amẹrika.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, ikọlu naa wa sopin lẹyin ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ arakunrin kan tawọn ọlọpaa mu jade lati inu ile itaja nla King Soopers.

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn ṣafihan iṣẹlẹ ni yajoyajo loju opo YouTube.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé

Ikọlu yi bẹrẹ ni nkan bi ago mejila abọ ọsan nigba ti afurasi yi wọ inu ile itaja naa to si bẹrẹ si ni yinbọn lu awọn eeyan.

Awọn ọlọpaa Boulder nibi to ti ṣẹlẹ fi soju opo Twitter ni nkan bi ogun iṣẹju ti iyinbọn yi bẹrẹ pe ''ikọlu n waye ni ile itaja King Sooper lopopona Mesa''

Lẹyin wakati meji si asiko yi, wọn fi ikilọ sita per ki awọn eeyan yago fagbegbe yi.

Ọrọ (Tweet) wọn ni Twitter tun kilọ pe ''Kawọn eeyan ma ṣe ṣafihan iroyin nipa bi ọlọpaa ṣe n koju afurasi yi sojuran araye''

Ṣugbọn diẹ lara bi ọlọpaa ṣe n doju ija kọ arakunrin naa lawọn eeyan kan to n kọja lẹgbẹ ile itaja naa ṣafihan

Ẹni to ya aworan naa n pariwo ''Mi o mọ nkan to n ṣẹlẹ...mo gb iro ibọn...eeyan kan ti subu lulẹ.Agbebọn ṣi wa nibẹ, ẹ maa sunmọ ibi''

Bo ṣe n sa kuro nile itaja naa laa n gbọ iro ibọn ninu fọnran fidio naa.

Bẹẹ si lo ṣe n ka nkan to n ṣẹlẹ titi di igba tawọn ọlọpaa de ti wọn si rọgba yika ile itaja naa.

Loju opo Twitter Gomina ipinlẹ Colorado, Jared Polis ba awọn mọlẹbi kẹdun iku awọn to ba iṣẹlẹ naa.

Ile ijọba White House ni wọn ti fi iṣẹlẹ naa to aarẹ Biden leti.