New Zealand mosques: Ẹmi 49 ló tí bá ìṣẹlẹ̀ iyìnbọn Christchurch lọ

Awọn oṣiṣẹ alaabo n tọju awọn to faragbọta

Oríṣun àwòrán, TV NEW ZEALAND

Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ alaabo n tọju awọn to faragbọta

Awọn alaṣẹ lorileede New Zealand ti kede pe ọdọmọkunrin ọmọ ọdun mejidinlọgbọn ọmọ orileede Australia kan yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun ipaniyan to ni ṣe pẹlu iyinbọn Christchurch.

Wọn ni yatọ si arakunrin yi,awọn ọkunrin meji miran ati obinrin kan lo wa ni ahamọ ti awọn si gba ohun ija oloro lọwọ wọn.

Wọn ko tidarukọ ọkunrin agbebọn naa ti wọn fura si pe o wa nidi iyinbọn naa

Saaju olootu ijọba orileede New Zealand kede pe eeyan mọkandinlaadọta lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn agbebọn yinbọn lu awọn to n kirun ni mọsalaṣi meji ni Christchurch.

Ọga ọlọpaa Mike Bush lorileede naa ti saaju fidi ọrọ mulẹ pe eeyan mẹrin ti wa ni ahamọ ṣugbọn awọn ko le sọ pato boya ẹlomiran wa to kopa ninu iṣẹlẹ ibi yi.

Àkọlé fídíò, Aarẹ ilẹ Amẹrika ni oun yoo koju agbebọn to pa ọmọ ile-iwe mẹtadinlogun ni Florida.
Àkọlé fídíò, Ìbúgbàmù ńlá ati iro ibọn gbalẹ ni ile itura Nairobi

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ fun awọn akọroyin pe niṣe ni awọn eeyan n sa asala fun ẹmi wọn ti ẹjẹ si kun ara awọn eeyan kan niwaju mọṣalaṣi Al Noor.

Awọn alaṣẹ ti fi ikilọ sita ki gbogbo mọṣalaṣi ti ilẹkun wọn gboingboin titi ti ọrọ yoo fi ni iyanju. Gbogbo awọn ile ẹkọ ni Christchurch naa ni wọn ti ti pa.

Ninu ọrọ rẹ si awọn ọmọ orileede naa,olootu ijọba Acinda Arden ni awọn ko ti mọ pato nnkan to ṣele, ṣugbọn ọjọ yi jẹ ''ọjọ buruku fun orileede New Zealand''

Aworan ibi ti awọn mọṣalaṣi naa wa
Àkọlé àwòrán, Aworan ibi ti awọn mọṣalaṣi naa wa

Mohan Ibrahim,to wa ni agbegbe mọṣalaṣi Al Noor sọ fun iwe iroyin New Zealand Herald pe ''Mo kọkọ ro wi pe ina ọba lo gbe awọn eeyan nigba ti mo ri ti awọn eeyan n sare kitakita''

''Awọn ọrẹ mi ṣi yi wa ninu mọṣalaṣi''

Mo ti n pe awọn ọrẹ mi lori ago ṣugbọn mi o ti gburo ọpọ ninu wọn. Mo n bẹru n fun ẹmi awọn ọrẹ mi''

Ọlọpaa kede pe awọn ti mu eeyan mẹrin

Ko ti daju iye agbebọn to kopa ninu iṣẹlẹ naa ṣugbọn ọga ọlọpaa ti sọ fun awọn akọroyin pe awọn ti mu eeyan mẹrin bayi; ọkunrin mẹta obinrin kan.

Iwe iroyin New Zealand Herald ti saaju ni ọkan lara awọn to yinbọn naa jẹ ọmọ orileede Australia ti o si kọ apilẹkọ eleyi ti o fi erongba rẹ si.

Aworan mọṣalaṣi Al Noor

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán, Aworan mọṣalaṣi Al Noor

Ninu rẹ o fi adisọkan rẹ han nipa titako gbigba awọn ara orileede miran wọ inu ilẹ wọn.

Fọnran fidio kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ ti jẹyọ nibi ti agbebọn naa ti n yinbọn lu awọn eeyan.

Ile iṣẹ ọlọpa ti parọwa si awọn ara ilu lati ma ṣe alabapin fọnran fidio naa