Texas Walmart shooting: Èèyàn ogún pàdánù èmi wọn ninu ìyibọ́npanìyàn El Paso

Àkọlé fídíò, Fọnran fidio awọn ọlọpaa nibi iṣẹlẹ naa

Eeyan ọgun ti dero ọrun lọwọ agbebọn ti eeyan mẹrindinlọgbọn si farapa ninu iyinbọnpaniyan kan to waye nilu El Paso Texas.

Gomina ipinlẹ naa lorileede Amẹrika ni iṣẹlẹ yi jẹ eleyi to buru julọ ti yoo ṣẹlẹ ni ibẹ.

Ile itaja Walmart kan to wa ni Cielo Vista Mall lẹgbẹ ibode ilẹ Amerika ati Mexico lo ti ṣẹlẹ.

Arakunrin ọmọ ọdun mọkanlelogun kan la gbọ pe o ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayi. Awọn ọlọpaa ni agbegbe Allen lo n gbe ni Dallas.

Kianna Long ati mọlẹbi rẹ kan to n rẹ lẹkun

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, ogun eeyan ṣagbako iku ojiji lọwọ agbebọn

Awọn oniroyin ilẹ Amerika kan ti sọ pe Patrick Crusius lorukọ rẹ.

Aworan CCTV to ṣafihan agbebọn naa nibi to ti wọ aṣọ dudu to si ti gbe ibọn dani ni wọn ti ṣe afihan rẹ lori amohunmaworan .

CCTV ṣafihan agbebọn to paniyan ni Texas

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aworan agbebọn to paniyan ni Texas

Aarẹ Amẹrika Donald Trump ti ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi iwa to buru

O kọ loju opo Twitter rẹ pe'' O dami loju pe emi ati awọn eeyan ilẹ yi jijọ n bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi. Ko si awijare kankan ti eeyan le ni lati fi gbẹmi alaiṣẹ''

Wọn ko ti darukọ awọn to farakasa ninu iṣẹlẹ naa amọ Aarẹ Mrexico sọ pe awọn ọmọ orilẹede oun mẹta wa ninu wọn gẹgẹ bi ile iṣẹ iroyin Reuters ṣe j'abọ.

Ipaniyan yi waye lẹyin isẹlẹ ti ilu California, nibi ti agbebọn kan ti pa eeyan mẹta nibi ayẹyẹ afihan ounjẹ kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: