Ìkọlù New Zealand: Jacinda, Alabi ati àwọn mii gboriyin

Aworan awọn tu wu iwa akin
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn to wu iwa akin lasiko ati lẹyin iṣẹlẹ naa re
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ati oore ati ika, ko si ikan ninu rẹ ti yoo gbe ni Yoruba a ma wi.

Ọrọ yi lo fẹ ṣe rẹgi pẹlu awọn ti wọn gba oriyin fun iwa akin ti wọn wu, lasiko iṣẹlẹ iyinbọn paniyan to waye ni Mọṣalasi meji lorileede New Zealand.

Kaakiri agbaye ni iroyin kan nipa iṣẹlẹ yii, ti awọn eeyan si ti n bu ẹnu atẹ lu arakunrin to wu iwa laabi yi.

Amọ bi ẹni to sisẹ ibi yii ti ṣe n gba eebu ati abuku, ni awọn kan n gba oriyin fun iwa akin ti wọn wu lasiko ati lẹyin iṣẹlẹ naa.

Wọnyi ni diẹ lara awọn ti awọn eeyan jakejado agbaye n gbosuba kare fun loju opo Twitter pe, wọn hu iwa akin lasiko ati lẹyin iṣẹlẹ naa.

Aworan eeyan to ku ninu iṣẹlẹ iyinbọnpayan New Zealand

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ẹni akọkọ to pade agbebọn naa re ni Mọṣalaṣi Al Noor

Daoudi Nadi

Oun ni ẹni ti wọn kọkọ darukọ pe o faragbọta ninu iṣẹlẹ naa.

Onimọ ẹrọ ni Daoud ti a si gbọ pe o bẹ si iwaju agbebọn naa, ki awọn eeyan to ku ba le ribi sa.

Ẹni ọdun mọkanlelaadọta nii ṣe.

Jacinda Arden

Aworan Jacinda Ardern

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba Jacinda Ardern ṣe gudugudu meje

Olootu ijọba orileede New Zealand ni Jacinda Ardern, ti o si ti gba oriyin lọdọ awọn eeyan kaakiri agbalaye fun ipa to ko lasiko iṣẹlẹ naa.

Oju ati ohun rẹ lori amohunmaworan ati loju opo ayelujara lawọn eeyan fẹrẹ damọ julọ lasiko iṣẹlẹ yii.

Ninu ọrọ ati iṣe rẹ, awọn eeyan loju opo Twitter ni o fihan pe, olori ti o ni ifẹ ara ilu nii ṣe.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Awọn Okunrin to koju agbebọn naa pẹlu gba oriyin

Eeyan pupọ la ri akọsilẹ pe wọn koju arakunrin to yinbọn pa awọn eeyan nigba ti ibọn wa lọwọ rẹ.

Ninu wọn la ti ri Naeem Rasheed, to jẹ ọmọ orileede Pakistan to padanu ẹmi rẹ .

Olootu ijọba orileede Pakistan Imran Khan, loju opo Twitter rẹ, gbosuba kare fun Naeem to si kede pe awọn yoo fi ami ẹyẹ to ga julọ da lọla.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ẹni keji ti a gbọ pe o koju agbebọn naa lanfaani lati sọ iriri rẹ fun awọn akọroyin, ti awọn eeyan si kan sara si oun naa.

Abdul Aziz jẹ ọmọ orileede Afghanistan sọ pe nigba ti oun gbọ iro ibọn, oun mu ẹrọ igba owo pelebe (atm card) ti oun si lẹ mọ agbebọn naa.

O ni oun mu ibọn agbebọn naa to jabọ, ti oun si gbiyanju lati yin mọ, ṣugbọn ibọn na ko dahun.

Aworan Aziz

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Abdul Aziz ni ohun ri nnkan ti ounṣe gẹgẹ bi ohun nla

Iyawo to sare pada lati doola ọkọ rẹ

Hosne Ara gbọ iro ibọn, to si sare lati doola ẹmi awọn obinrin ati awọn ọmọde to wa ni ile ijọsin naa.

O pade iku rẹ nigba to sare lati lọ doola ọkọ rẹ, ti ko le rin to wa laaye awọn ọkunrin.

Ọkọ rẹ ribisa asala ṣugbọn Hosne ko si ọwọ agbebọn ọhun, ti o si yinbọn pa.

Imaamu Ọmọ Naijiria Alabi Lateef

Imamu yi lo kọkọ ri agbebọn naa ni Mọṣalasi Linwood, ti o si figbe ta si awọn janmọ rẹ lati sapamọ fun agbebọn naa.

Nitori pe o ṣe akiyesi yi, pupọ awọn to wa nibẹ ni wọn ribi sa jade, ti iku si re ori wọn kọja.

Lateef Alabi ati awọn eeyan miran

Oríṣun àwòrán, @GbenroAdegbola

Àkọlé àwòrán, Lateef Alabi ti gba oriyin lọdọ awọn eeyan kaakiri agbaye

Aworan Lateef jẹ eleyi ti ọpọ eeyan ri pẹlu aṣọ rẹ ti o kun fun ẹjẹ.

Awọn eeyan wa kan saara si fun iwa akin ti o wu yii.

dmkunrin to fọ ẹyin mọ aṣofin lori ni Ausralia

Will Connoly ni orukọ ọmọkunrin to fọ ẹyin mọ asọfin orileede Australia kan, Sẹnatọ Fraser Anning lori, nibi ti o ti n sọrọ.

Fraser Anning ti kọkọ kọ iwe kan sita, nibi ti o ti sọ pe ko si ohun to buru ninu ipaniyan to waye ni New Zealand.

Iwa ti Will Connoly yii wu, mu ki awọn eeyan kan, kan saara si pe o ṣe e daa.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Amọ, awọn oludari oju opo ikansira ẹni Twitter, ti sọ agadagodo si oju opo rẹ, ti wọn si ti pa fun iwa to wu yii.