France: Macron kéde ìgbé ayé ìdẹ̀rùn àti àdínkù owó orí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron ti ṣeleri lati mu ki owo oṣu awọn oṣiṣẹ pọ si.
Macron, ninu ọrọ kan to ba awọn ọmọ orilẹede naa sọ lori amohunmaworan sọ pe, adinku yoo ba iye owo ori ti awọn eniyan n san gẹgẹ bi èsì si iwọde ati ifẹhonu han to n waye.
Lati ọsẹ mẹẹrin ni iwọde alagbara ti n waye tako èlé to gun ori owo ori epo, ọwọn owo ọja, ati awọn nkan mi i.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àpapọ̀ owó táwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣòfin ń gbà rèé
- ‘A ti yọ ọwọ́ lọ́rọ̀ Ààrẹ Buhari fún sáà kejì’
- Ìyàtọ̀ wà nínú ìlépa àwọn òṣèré tíátà ayé àtijọ́ àti ìsisìnyí-Papalolo
- Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò gé orí ọmọ aládùúgbò torí ₦200,000 owó ìkómọ
- PDP, EFCC tako ara wọn lórí àyẹ̀wò ilé ọmọ Atikuu
- Bàbá ọmọ tí Mammadou Gassama dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ lọ ẹ́wọ̀n
Bi awọn ifẹhonuhan naa ṣe lọ niyii:
Ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kọkanla ni wọn kọkọ bẹrẹ. Igba le mejilelọgọrin ẹgbẹrun ni awọn to kopa. Eniyan kan padanu ẹmi rẹ, irinwo le mẹsan farapa, mẹtalelaadọrin si wa ni ihamọ ọlọpa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹwẹ, awọn ẹgbẹrun mẹrindinlaadọsan eniyan tun tu jade labẹ aburada ifẹhonuhan naa ti wọn pe ni 'Yellow Vest', ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla.
Eniyan mẹrinlelọgọrin lo farapa, awọn ọlọpa si mu ọọdun le meje sahamọ.
Bakan naa ni nkan tun ri lọjọ kini, oṣu Kejila nigba ti ẹgbẹrun mẹrindinlogoje jade lati fẹhonu han.
Awọn ojilelẹgbẹta din mẹwa ni awọn ti ọlọpa mu, ti eniyan ọtalerugba le mẹta si farapa.
Ifẹhonuhan to kẹhin waye lọjọ kẹjọ, oṣu kejila bakan naa, ẹgbẹrun mẹrindinlogoje jade lati fẹhonu han.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara wọn ni awọn agbofinro ti mu okoolelẹgbẹfa si ahamọ wọn. Awọn mejidinlọgọfa lo farapa.
Aarẹ Macron ninu ọrọ rẹ bu ẹnu ẹtẹ lu iwa jagidijagan to waye ọhun, ṣugbọn o sọ pe 'ibinu awọn olufẹhonuhan ọhun lagbara, o si jẹ eyi to ba ofin mu.''
Pẹlu ileri tuntun yii, ọgọrun Euro ni yoo gun ori owo oṣu oṣiṣẹ l'oṣooṣu lati ọdun 2019.
Bakan naa lo sọ pe wọn yoo fagile afikun to ba owo ori ti awọn oṣiṣẹfẹhinti ti owo wọn kere, ti wọn yoo si rọ awọn agbanisiṣẹ lati san ajẹmọnu opin ọdun ti wọn ko ni yọ owo ori lara rẹ fun awọn oṣiṣẹ .














