Northern Elders Forum: Ààrẹ Buhari kò gbọdọ̀ díje lẹ́ẹ̀kejì

Oríṣun àwòrán, Sambokhan Giwa
Ajọ Northern Elders Forum lorilẹede Naijiria ti sọ wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko gbọdọ du ipo aarẹ fun saa keji lorilẹede Naijria.
Alaga ajọ naa, Ọjọgbọn Ango Abdullahi lo sọ bẹẹ fun BBC lasiko ti wọn n fi ero wọn han.
Abdullahi ni ko si idagbasoke rara lagbegbe ariwa orilẹede Naijria lati igba ti aarẹ Buhari ti gori oye, afi ebi ati isẹ lo wọpọ si lawujọ wọn.
Ajọ naa bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ oselu APC ati gomina wọn lẹkun naa nitori wọn ni kosi ilọsiwaju lasiko wọn.
Amọ, igbakeji aarẹ ẹgbẹ to n bojuto aabo labẹ aarẹ Buhari, Muhammad Muhammed Muhammad bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Ajọ Northern Elders Forum naa fun igbese wọn lati tako Aarẹ Muhammadu Buhari.









