America fẹ́ẹ́ pa mi nínú ìkọlù, wọ́n ní Boko Haram ni mi-Sheikh Gumi

Sheikh Ahmad Gumi

Oríṣun àwòrán, Sheikh Ahmad Gumi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja Aafaa ilu Kaduna nni, Sheikh Ahmad Gumi,ti kede pe oun wa lara awọn eeyan ti ilẹ America fẹ pa danu pẹlu ado oloro, ninu ikọlu wọn si ipinlẹ Sokoto lọjọ ọdun Keresimesi to kọja.

Idi eyi bi aafaa ti ẹnu ki i sin lara rẹ lori ọrọ awọn agbesunmmọmi naa ṣe wi ni pe, America ti ka oun mọ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ti wọn fẹ doju ija kọ.

Gumi sọrọ yii ninu fidio kan lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ. Ẹnikan to pe ara rẹ ni #General_Somto, lo si gbe e jade loju opo X rẹ lọjọ Aiku, ana.

Sheikh Gumi sọ nibẹ pe oun gba ipe kan lowurọ kutu, ẹni to pe naa ko sọ orukọ ara rẹ, ṣugbọn o fi to oun leti pe ipade apapọ lori eto aabo kan fẹ waye l'Abuja.

"Awọn olori apa Ariwa atawọn ẹlẹsin gbọdọ sọrọ tako irọ gbuu ti wọn pa mọ mi"

Gẹgẹ bi Sheikh Gumi ṣe wi, "Mo gba ipe kan lati ọdọ ọga agba kan l'Abuja, o sọ fun mi pe mo wa lara awọn ti wọn ti ya sọtọ lati pa ninu ikọlu America, pe gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ti mo jẹ.

"Awọn olori apa Ariwa atawọn ẹlẹsin gbọdọ sọrọ tako awọn irọ yii. Irọ gbuu ni wọn pa mọ mi"

Gumi ni America n kede pe oun fẹ gba Naijiria la, lati ba awọn agbesunmọmi ja, ṣugbọn awọn gan-an ni agbesunmọmi.

"America naa n sọ pe oun wa sibi lati ba awọn agbesunmọmi ja, awọn wo wa ni agbesunmọmi? Awọn naa ni"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sheikh Gumi ṣalaye pe America gan-an kopa to pọ ninu bi Boko Haram ṣe bẹrẹ.

O fi kun un pe ai si aabo ni Naijiria ko ṣẹyin awọn ilẹ okeere yii, to n gbe owo fun awọn agbesunmọmi, paapaa, ijọba Aarẹ Donald Trump.

Bakan naa lo koro oju si aisọrọ soke awon olori ẹsin lapa Ariwa, pẹlu bi ikọlu ṣe n waye nibẹ to.

"Ẹyin Ariwa, gbogbo yin lẹ mọ bi wọn ṣe n kọlu wa, ṣugbọn nibo ni awọn olori yin wa, ki ni wọn si ti ṣe si. ?"

Gumi lo beere bẹẹ.

Gumi ko ṣai sọ pe awọn Kristẹni nikan lo maa n ri iranlọwọ gba nigba ti ikọlu ba waye, o ni eyi ko yẹ ko ri bẹẹ.

Bi awọn to n gbe iranwọ oun kalẹ ko ba le fun gbogbo Naijiria, ki wọn maa mu nnkan wọn lọ ni Gumi sọ.

Tẹ o ba gbagbe, oru ọjọ Keresimesi to kọja ni America kọlu apa kan ibi ti wọn ni awọn agbesunmọmi to n ṣoro nipinlẹ Sokoto, wa, pẹlu alaye pe ikọlu naa ko ṣẹyin aṣẹ Aare ijọba America.

Latigba naa si ni Sheikh Gumi ti n koro oju si ikọlu ọhun, o ni America ki I ṣe olugbala Naijiria, ko yẹ kijọba wa beere iranlọwọ lọwọ wọn.