Ààrẹ Tinubu pàṣẹ káwọn olórí ogun wá àwọn agbébọn tó pa èèyàn tó lé lógójì nípìnlẹ̀ Niger jáde

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/ X/ ZAKARI Kontagora
Latari ikọlu awọn agbebọn si agbegbe Kasuwan Daji, ipinlẹ Niger, nibi ti wọn ti pa eeyan to le logoji lọjọ Abamẹta, ti wọn tun ji ọpọ gbe lọ, Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe kawọn olori ogun wa awọn amookunṣika naa jade.
Ana ọjọ Aiku, ọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii ni Tinubu paṣẹ naa, ninu atẹjade to funra rẹ buwọlu.
Tinubu dari aṣẹ naa si Minisita eto aabo, Olori awọn ẹṣọ alaabo, awọn ọga ologun ẹka kọọkan, ọga ọlọpaa patapata ati adari ẹka ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede yii.
O ni awọn apaayan naa ti tan Naijiria ni suuru, won si gbọdọ jiya ẹṣẹ iwa ọdaran wọn.
"Awọn agbesunmọmi yii ti dan Naijiria ati awọn eeyan rẹ wo, wọn gbọdọ jiya rẹ ni kikun.
"Iru ẹni yowu ki wọn jẹ, abi ohun yowu ti ero ọkan wọn jẹ, a gbọdọ dọdẹ wọn ka mu wọn.
"Bakan naa, awọn to n ṣe agbodegba fun wọn naa gbọdọ foju wina ofin."
Bẹẹ ni Aare Bola Tinubu wi.
Bakan naa lo paṣẹ pe ki wọn wa ọna ti wọn yoo fi gba awọn to wa nigbekun ajinigbe naa silẹ, ki eto aabo si nipọn si i ni awọn agbegbe naa.
'Asiko iṣọkan ni a wa yii, a gbọdọ jọ koju awọn ẹhanna yii ni'
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Tinubu sọ pe ikọlu atigbadegba yii, gba ki gbogbo eeyan pata dide bii ọmọniyan, lati jọ koju awọn ẹhanna to n pa eeyan ṣere.
"Asiko yii gba fifi ọmọniyan ṣe, a gbọdọ duro niṣọkan ka si koju awọn ẹhanna yii.
"Bi a ba sowọpọ, a le ṣe e, a si gbọdọ ṣẹgun wọn .A gbọdọ gba alaafia pada fun awọn ilu ti wọn kọlu yii''
Bẹẹ ni Aarẹ wi, to si gbadura fun awọn eeyan to padanu ẹmi ninu ikọlu naa.
Ki lo ṣẹlẹ ṣiwaju?
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni ọdun tuntun 2026 yii ni awọn apaayan kan ya bo ilu ti a mọ si Kasuwan Daji, nipinlẹ Niger.
Kasuwan Daji yii ko fi bẹẹ jinna si Papiri, nibi ti awọn agbebọn ti ji olukọ ati akẹkọọ to le ni ọọdunrun lọ lọṣu Kọkanla ọdun 2025 to kọja.
Ile ẹkọ St Mary's, to jẹ ti ijọ Aguda ni wọn wọ loru moju nigba naa ti wọn fi ko awọn eeyan rẹpẹte lọ.
Rabaraba iṣẹlẹ naa ko ti I kuro nilẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe oṣu to kọja yii ni awọn ti wọn ji gbe naa ṣẹṣẹ gba itusilẹ tan, ki awọn agbesunmọmi too tun wa pa wọn mọle ni Kasuwan Daji lọjọ Abamẹta.
Gẹgẹ bi awọn araalu Kasuwan Daji to ba BBC sọrọ ṣe ṣalaye, yatọ si pe awọn apaayan naa dana sun ilu, niṣe ni wọn so awon eeyan mọlẹ bii ẹran.
Nibi ti wọn so wọn mọ ni won ti n du wọn lọrun bii adiẹ, wọn si yinbon pa awọn elomi-in nibẹ.
Lẹyin eyi ni wọn tun ko awon araalu kan wọgbo lọ, ti ẹnikẹni ko si ti I gbọ nipa won lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Ẹ o ranti pe ipinlẹ Niger yii wa lara awọn ipinlẹ Oke ọya to n koju ikọlu awọn agbesunmọmi, ti ijọba si fi n da wọn loju pe eto aabo yoo pada fẹsẹ mulẹ.
Lasiko yii, inu ibẹrubojo ni awon olugbe agbegbe ti ikọlu ti waye yii wa, wọn ko si fẹ ba awọn akoroyin gan-an sorọ mo nitori ẹru to n ba wọn
Won ni ki awon ẹruuku naa ma tun lọ pada waa pa awọn mọle.
Ẹwẹ, atẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Niger, Wasiu Abiodun fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìíní fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé èèyàn tó lé ní ọgbọ̀n ni wọ́n ṣekúpa níbi ìkọlù náà.
Bákan náà ló sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn, táwọn kò ì tíì le fìdí iye wọn múlẹ̀ ni àwọn agbébọn náà tún jí gbé.














